Back to Africa Check

Ǹjẹ́ àwọn ọmọ orílẹ̀dè Nàìjíríà lè ṣị́ SIM inú fóònù wọn tí wọ́n tìpa láìní nọ́mbà ìdánimọ̀? Rárá, ìtànjẹ ni àtẹ̀ránṣẹ́ yìí

“Tí sim rẹ bá wà lára méjìlélàádórin mílíònù sim tí àjo NCC tìpa, ìgbésè kan ṣoṣo ló kù fún ọ láti ṣí sim rẹ ní ọ̀fẹ́,” àtẹ̀ráṇsẹ́ kan tí ó ń káàkiri lórí Facebook ní orílẹ̀dè Nàìjíríà ní oṣù kẹ́rin ọdún 2022 ni ó kà báyìí.

Nigerian Communications Commission (NCC), àjọ tí ó ń fi òfin ṣe ìtósọ́nà àwọn oníṣé ìbáraenisọ̀rọ̀ ní orílẹ̀dẹ̀ Nàìjíríà.

Àtẹ̀ránṣé náà sope àwọn tó ní fóònù alágbéká tí wọ́n ti SIM kaàdì inú rẹ̀ pa lè ṣi nípa títẹ link tí ó wà nínú àtèránṣé òhún.

“Yára nísinsìnyí láti ṣí tìrẹ, èmi ṣè ṣí mẹ́ta nínú sim mi ní ọ̀fẹ́̀. Má ṣahun, firánṣẹ́ sí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ àti ẹgbẹ́ tí o bá wà,” ó ṣàfikún.

Ní oṣù kẹ́rin, ààrẹ orílẹ̀dẹ̀ Nàìjíríà Muhammadu Buhari bọwọ́lu ètò ìlànà iṣé tí ó fún àwọn oníṣé ìbáraenisọ̀rọ̀ ní agbára láti ti àwọn SIM kaàdì tí won kò ní nọ́mbà ìdánimọ̀ ìyẹn national identification number (NIN) pa.

Ìṣirò méjìlélàádórin mílíònù SIM ni wón tìpa, tí ó sì jẹ́ wípé àwọn tí ó ni SIM wọ̀nyí kò lè lo fóònù wọn.

Ṣùgbọ́n ṣé wón lè ṣí SIM wọn nípa lílo link tí ó wà nínú àtẹ̀ránṣẹ́ náà? A ṣè ìwádìí.

SIM card

NCC: Ẹ kọ etí ikún sí àtẹ̀ránṣẹ́ tí ó ní ‘bákan bàkan’ nínú

Ní ọjọ́ kọkọ̀nlá oṣù kẹ́rin ni àjọ NCC tẹ gbólóhùn àlàyé  jáde tí ó ń ṣe ìkìlọ̀ lórí àtẹ̀ránṣẹ́ tí ó gbòde kan yìí.

“Link yìí àti àwọn àlàyé ti ó farapẹ́ ìròyìn tí kò lóòtọ́ nínú àti ìròyìn tí ó ní ẹ̀tàn nínú ni a gbékalẹ̀ ní ọ̀nà tí ó lè ṣi àwọn ará ìlú lọ́nà nípa àwọn SIM kaàdì tí a tìpa, tí kò sì le pè jáde, nítorí wọn kò so wọ́n pọ̀ mọ́ NIN kí àsìkò tí wọ́n là kalẹ̀ tó pé,” gẹ́gẹ́ bí gbólóhùn òhún ti sọ.

“Ìròyìn tí ó lè ṣi ni lọ́nà tí ó ti káàkiri yìí ní àmì ìdánimọ̀ ti àjọ NCC tí ó si ń sèlérí ìdánilójú fún àwọn ará ìlú wípé tí wọ́n bá lè tẹ link wẹ́ẹ̀bù tí wọ́n sì tẹ̀lé àwọn ìlànà tó ní ṣe pèlú rẹ̀, àwọn tí wọ́n ti SIM kaàdì wọn pa lè ṣi SIM wọn lábẹ́ èyíkéèyí nẹ́tíwokì fóònù alágbéká láì ní NIN tí ó jẹ́ ojúlówó.

Gbólóhùn náà sàfikún wípé àtẹ̀ránṣe náà kò ti ọwọ́ NCC wá, àti wípé àjọ náà kò sọfún àwọn ará ìlú pé wọ́n lè ṣí SIM won láì ní NIN.

“Fún ìdí èyí, kí ẹnikẹ́ni má fiyè sí àtẹ̀ránṣẹ́ náà.”̀

Ọ̀nà àti lu ni ní jìbìtì

Links tí ó wà nínú àtẹ̀ránṣẹ́ náà lo sí búlóògì tí ó sọfún àwọn ènìyàn kí wọ́n fi nọ́mbà fóònù wọn sílẹ̀ láti lè gba airtime àti data ọ̀fẹ́.

URL tí ó ní àṣìkọ tàbí tí kò pé jẹ́ àmì pé wọ́n lè fẹ́ lu ni ní jìbìtì- Jìbìtì lórí èrọ ayélujára lè dàbí ẹnipé ó wá láti orísun tí ó jẹ́ ojúlówó, tí ó sì ní kí àwọn ènìyàn fi àwọn ohun ìdánimọ̀ wọn sílẹ̀. Léyìí tí ó lè já sí jíjí ìdánimọ̀ ẹni lá ti fi lu jìbìtì.

Republish our content for free

Please complete this form to receive the HTML sharing code.

For publishers: what to do if your post is rated false

A fact-checker has rated your Facebook or Instagram post as “false”, “altered”, “partly false” or “missing context”. This could have serious consequences. What do you do?

Click on our guide for the steps you should follow.

Publishers guide

Africa Check teams up with Facebook

Africa Check is a partner in Meta's third-party fact-checking programme to help stop the spread of false information on social media.

The content we rate as “false” will be downgraded on Facebook and Instagram. This means fewer people will see it.

You can also help identify false information on Facebook. This guide explains how.

Add new comment

Restricted HTML

  • Allowed HTML tags: <a href hreflang> <em> <strong> <cite> <blockquote cite> <code> <ul type> <ol start type> <li> <dl> <dt> <dd> <h2 id> <h3 id> <h4 id> <h5 id> <h6 id>
  • Lines and paragraphs break automatically.
  • Web page addresses and email addresses turn into links automatically.
limit: 600 characters

Want to keep reading our fact-checks?

We will never charge you for verified, reliable information. Help us keep it that way by supporting our work.

Become a newsletter subscriber

Support independent fact-checking in Africa.