Back to Africa Check

Àwọn ọjọ́ ètò ìdìbò orílẹ̀dè Nàìjíríà ti ọdún 2023 kò yípadà, ó lòdì sí ohun tí wọ́n sọ lóri àwọn òpó ìkànsíaraẹni

“INEC kéde àwọn ọjọ́ ètò ìdìbò gbogboògbò ti odún 2023,” ìfiránṣẹ́ ní oṣù kéje ọdún 2022 tí a gbé sórí ẹgbé Facebook kan tí ó lé ní 280,000 èèyàn wà ni ó bèrè báyìí.

Independent National Electoral Commission (Inec) ni àjọ tí ó ń ṣe alákóso ètò ìdìbò ní orílẹ̀dè Nàìjíríà.

Ìfiránṣẹ́ náà sọpé ètò ìdìbò gbogboògbò ti orílẹ̀dè Nàìjíríà ti ọdún 2023 láti yan ààrẹ, igbá kejì aàrẹ, àti àwọn ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin kékeré àti ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà tí yíò wáyé ní ọjọ́ kẹjìdínlógún oṣù kejì ọdún 2023.

“Tí ti àwọn gómínà àti àwọn ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ yíò wáyé ní ọjọ́ kẹ́rin oṣù kẹ́ta ọdún 2023,” ó sàfikún.

A rí irú ìfiránṣẹ́ tí ó farapẹ́ èyí ní orí Facebook ní ibí, ibí, ati ibí.

Ǹjé òótọ́ ni ètò ìdìbò tí ó ń bò lórílèdè Nàìjíríà yíò wáyé ní àwọn ọjọ́ wọ̀nyìí? A ṣe ìwádìí.

INEC_false

Ètò ìdìbò gbogboògbò ti orílẹ̀dè Nàìjíríà yíò wáyé gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti sètò rẹ̀ tẹ́lẹ̀

Ọjọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n oṣù kejì ọdún 2022 ni àjọ Inec ti gbé ìwé ìlànà àti ètò àwọn ohun tí ó yẹ ní ṣíṣe fún ètò ìdìbò gbogboògbò ti ọdún 2023 sí orí ayélujára. Nínú rẹ̀ ni àwọn ọjọ́ àwọn ìgbésẹ̀ tí ó ṣe gbòógì tí yíò wáyé sáájú ètò ìdìbò àti ètò ìdìbò fún ra rẹ̀ wà.

Ìwé ìlànà òhún fihàn wípé ìdìbò yíyan ààrẹ àti àwọn ọmọ ilé ìgbìmọ̀ asòfin (kékeré at̀i àgbà) yíò wáyé ní ọjọ́ káàrùndínlọ́gbọ̀n oṣù kejì ọdún 2023.

Ìdìbò yíyan gómínà àti àwọn ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ yíò wáyé ní ọjọ́ kọkọ̀nlá oṣù kẹ́ta.

Ìfiránṣẹ́ orí Facebook yìí kò mẹ́nu ba ìgbà àti ìdí tí àjọ Inec fi yí àwọn ọjọ́ gbòógì wònyìí padà lóri kàléndà ètò ìdìbò.

A wo webusite àti àwọn òpó ìkànsíaraẹni ti àjọ Inec ṣùgbọ́n a kò rí ibi tí wọ́n ti mẹ́nu ba ọjọ́ ìdìbò tuntun. 

Àwọn oníròyìn ìbílẹ̀ yíò ti gbé ìròyìn ìyípadà pàtàkì báyìí tí ó bá jé òótó àmó a kò rí èrí pé wọ́n ṣe èyí.

Irú ìròyìn tí kò lóòtó nínú báyìí lè mú kí àwọn olùdìbò sọ ẹ̀tọ́ won láti dìbò yan ẹni tí ó wù wọ́n nù, àti láti kópa nínú ìjọba tiwa n tiwa.

 

 

Republish our content for free

We believe that everyone needs the facts.

You can republish the text of this article free of charge, both online and in print. However, we ask that you pay attention to these simple guidelines. In a nutshell:

1. Do not include images, as in most cases we do not own the copyright.

2. Please do not edit the article.

3. Make sure you credit "Africa Check" in the byline and don't forget to mention that the article was originally published on africacheck.org.

For publishers: what to do if your post is rated false

A fact-checker has rated your Facebook or Instagram post as “false”, “altered”, “partly false” or “missing context”. This could have serious consequences. What do you do?

Click on our guide for the steps you should follow.

Publishers guide

Africa Check teams up with Facebook

Africa Check is a partner in Meta's third-party fact-checking programme to help stop the spread of false information on social media.

The content we rate as “false” will be downgraded on Facebook and Instagram. This means fewer people will see it.

You can also help identify false information on Facebook. This guide explains how.

Add new comment

Restricted HTML

  • Allowed HTML tags: <a href hreflang> <em> <strong> <cite> <blockquote cite> <code> <ul type> <ol start type> <li> <dl> <dt> <dd> <h2 id> <h3 id> <h4 id> <h5 id> <h6 id>
  • Lines and paragraphs break automatically.
  • Web page addresses and email addresses turn into links automatically.
limit: 600 characters

Want to keep reading our fact-checks?

We will never charge you for verified, reliable information. Help us keep it that way by supporting our work.

Become a newsletter subscriber

Support independent fact-checking in Africa.