Back to Africa Check

Àwòrán ọ̀nà kan ní orílẹ̀dè Pakistan, kìí ṣe ọ̀nà Ughelli-Asaba tí wọ́n dáwọ́lé lórílẹ̀dè Nàìjíríà

NÍ ÈDÈ KÚKÚRÚ: Àwòrán kan tí ó ń káàkiri ní orílẹ̀dè Nàìjíríà pẹ̀lú ọ̀rọ̀ àhésọ kan pé ó ń sàfihàn pópónà márosẹ̀ tí ó wà láàrín ìlú Ughelli àti Asaba ní ìpínlè Delta, tí wọ́n sì sọ wípé gómínà Ifeanyi Okowa ni ó ṣé. Ṣùgbọ́n eléyìí jẹ́ ìgbìyànjú láti túbọ̀ jẹ́ kí Okowa di ìlú mòóká, ní pàtàkì bí ó ṣe gbé àpótí láti di igbákejì ààrẹ orílẹ̀dè Nàìjíríà ní ètò ìdìbò 2023. Àwòrán náà sàfihàn pópónà márosẹ̀ kan ní orílẹ̀dè Pakistan, kìí se orílẹ̀dè Nàìjíríà.

 

 

Àwòrán kan tí wọ́n tẹ̀ ránṣẹ́ lórí ẹgbẹ́ kan lórí Facebook ní orílẹ̀dè Nàìjíríà ní oṣù kẹsan ọdún 2022 pẹ̀lú ọ̀rọ àhésọ pé ó ń sàfihàn pópónà márosẹ̀ Ughelli-Asaba tí wọ́n ti parí iṣé lórí ní ìpínlẹ̀ Delta, ní apá gúúsù orílẹ̀dè Nàìjíríà.

Àkólé rẹ̀ kà báyìí: Oṣé o gómínà Ifeanyi A. Okowa fún yíyára láti dá sí àti parí pópónà márosẹ̀ Ughelli-Asaba láàrín ọdún mẹ́j̣ọ rẹ lórí àléfà.

 Asaba jẹ́ olúìlú ìpínlẹ̀ Delta, tí Ughelli sì jẹ́ ìlú tí ó wà ní ibùsọ̀ adọsan sí apá gúúsù ìwò-oòrùn.

Ifeanyi Okowa jẹ́ gómínà àti igbá kejì ààrẹ lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party nínú ètò ìdìbò tí yíò wáyé ní orílẹ̀dè Nàìjíríà ní ọdún 2023. Àtẹ̀ránṣẹ́ orí Facebook ọ̀hún ní ìtọ́kasí tí ó lọ sí ojú ìwé ti Okowa gangan lórí Facebook nínú.

Ìjọba àná ti Emmanuel Uduaghan ní ọdún 2007 ni ó dáwọ́lé pópónà mároṣẹ̀ olójú méjì ti Ughelli-Asaba. Sùgbọn, ìjọba Okowa ṣẹ̀ fọwọ́sí píparí ọ̀nà náà ní ọdún 2019.

Wọ́n tẹ àwòrán náà ránṣẹ́ ní orí Facebook ní ibí, ibí àti ibí.

Ǹjẹ́ àwòrán tí wọ́n gbé sórí òpó ìkànsíaraẹni yìí sàfihàn pópónà mároṣè Ughelli-Asaba tí wọ́n ti parí? A se ìwádìí.

HighwayNigeria_False

Àwòrán pópónà Hazara ní orílẹ̀dè Pakistan

A tọ pinpin àwòrán náà látẹ̀yìnwá lórí Google, ó sì gbé wa lọsí àkójọpọ̀ àwòrán ti búlọ̣́ọ̀gì arìnrìnàjò ti orílẹ̀dè Pakistan kán gbé sórí Pinterest ní oṣù kẹsan ọdún 2020. Níbi tị wọ́n fi ọ̀nà náà hàn gẹ́gẹ́ bi pópónà márosẹ̀ Hazara ní orílẹ̀dè Pakistan tí ó wà ní apá gúúsù ilẹ̀ Asia.

A wá “pópóǹa márosẹ̀ Hazara” lórí ẹ̀rọ Google, ó sì tọ́ka wa sí àwọn àwòrán ọ̀nà náà, léyìí tí ó sàfihàn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi pópónà Hazara. Kíkọ́ pópónà márosẹ̀ oní ibùsọ̀ ọgọsan yìí bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 2014 tí wọ́n sì ṣe ìfilọ́lẹ̀ rẹ̀ ní àárín ọdún 2020

Ní oṣù kejì ọdún 2022, ó jáde nínú ìròyìn pé àwọn arìnrìnàjò fi ẹ̀hónú wọn hàn lórí àìbìkítà nípa pópónà márosè. Ughelli-Asaba. Ṣùgbọ́n a kò rí ìròyìn kànkan tí kòì pẹ́ lórí ibi tí wọ́n bá ṣ́e dé ní ọ̀nà náà, bẹ́ẹ̀ sì ni kò sí èyí tí ó ń sọwípé wọ́n ti parí ọ̀nà náà. 

Àwòrán tí ó ń káàkiri lórí òpó ìkànsíaraẹni ní orílẹ̀dè Nàìjíríà kò sàfihàn pópónà mároṣẹ̀ Ughelli-Asaba, kì dẹ̀ kín ṣe orílẹ̀dè Nàìjíríà ni wọ́n ti ya àwòrán náà. Wọn kò tíì parí iṣẹ́ lóri pópónà márosẹ̀ tí ó wà láàrín Ughelli àti Asaba ní ìpínlẹ̀  Delta.

 

 

 

For publishers: what to do if your post is rated false

A fact-checker has rated your Facebook or Instagram post as “false”, “altered”, “partly false” or “missing context”. This could have serious consequences. What do you do?

Click on our guide for the steps you should follow.

Publishers guide

Africa Check teams up with Facebook

Africa Check is a partner in Meta's third-party fact-checking programme to help stop the spread of false information on social media.

The content we rate as “false” will be downgraded on Facebook and Instagram. This means fewer people will see it.

You can also help identify false information on Facebook. This guide explains how.

Further Reading

Add new comment

Restricted HTML

  • Allowed HTML tags: <a href hreflang> <em> <strong> <cite> <blockquote cite> <code> <ul type> <ol start type> <li> <dl> <dt> <dd> <h2 id> <h3 id> <h4 id> <h5 id> <h6 id>
  • Lines and paragraphs break automatically.
  • Web page addresses and email addresses turn into links automatically.
limit: 600 characters

Want to keep reading our fact-checks?

We will never charge you for verified, reliable information. Help us keep it that way by supporting our work.

Become a newsletter subscriber

Support independent fact-checking in Africa.