Back to Africa Check

Kò sí èrí tó kúnjúwọ̀n tó fihàn pé èso soursop ń wo ààrùn jẹjẹrẹ

NÍ ÈDÈ KÚKÚRÚ: O ò ní láti rìn jìnà kí o tó rí awogba ààrùn tí wọ́n ní ó ń wo ààrùn jẹjẹrẹ. Ṣùgbọ́n bí ó ti lẹ̀ jẹ́ wípé ìwádìí lórí èso soursop ń dàbí pé ó lè ní àṣeyọrí nínú, kò sí èyíkeyìí nínú rẹ̀ tí ó ti fi òntẹ̀ lu èso soursop gẹ́gẹ́ bi “ìwòsàn” fún ààrùn jẹjẹrẹ àti pé àwọn kan ti lọ sí ẹ̀wọ̀n lórí pé wọ́n díbọ́n pé ó lè wo ààrùn náà sàn.

Ní oṣù kọ́kọ̀nlá ọdún 2022, ẹgbẹ́ orí Facebook kan tí wọn pè ní The Alkaline Momma gbé fídíò kan síta, tí ó sì ń sọ nínú rẹ̀ pé èso soursop, èso tí wọ́n ma ń sábà ń rí nínú igbó òjò tí ó sì jẹ ẹbí kustard apù, lè ṣètọ́jú ààrùn jẹjẹrẹ. 

Àkọ̀rí tí ó wà nínú fídíò ọ̀hún ń polówó ǹkan kan tí wọ́n fi èso soursop ṣe lórí webusite alternative health group. Tí ó tó èèyàn ẹgbẹ̀rún mẹ́fà ti wò.

 Àwọn àtẹ̀ránṣẹ́ tí ó ń sọ irú ọ̀rọ̀ yìí ti tàn káàkiri orí àwọn òpó ìkànsíaraẹni, ní ọ̀pọ̀ ìgbà bi ìpolówó àwọn ǹkan tí wọ́n fi èso soursop ṣe. Àtẹ̀ránṣẹ́ orí Facebook kan sọpé èso òhún “lágbára ju kimotẹ́rápì lọ ní ìwọn ẹgbẹ̀rún”.

Irú ọ̀rọ̀ àgbàsọ nípa ìlera báyìí ti ní ẹgbẹ́ tirè lórí Facebook, tí wọ́n yàsọ́tọ̀ láti ma tẹ ìròyìn tí ó ń dàgbà si àti ọ̀rọ̀ tí wọ́n pè ní “èsì ìwádìí àwọn onímọ̀ sáyẹ́nsì láti fi gbe ọ̀rọ̀ tí wọn bá sọ nípa ìlera nídìí”.

Ṣé àwọn ọ̀rọ̀ àgbàsọ yìí ní àtìlẹyìn àwọn onímọ̀ sáyẹ́nsì? A sàyẹ̀wò rẹ̀.

Soursop_False.png

Ìwádìí tí ó ní àmì àseyọrí nínú… lára eku àti nínú ìgò àyẹ̀wò

Èso soursop ni a tún pè ní gaviola ní èdè gẹ̀ẹ́sì, tí a ma ń rí ní igbó òjò káàkiri ilẹ̀ adúláwọ̀, gúúsù ìlà oòrùn ilẹ̀ Asia àti gúúsù ilẹ̀ Amẹ́ríkà, Nínú ìṣègùn ìbílẹ̀, oríṣiríṣi ẹ̀yà ara ọ̀gbìn náà, tí ó fimọ́ èso rẹ̀, ni wọ́n ti lò láti ṣe ìtọ́jú oríṣiríṣi ààrùn. 

 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwádìi ni wọ́n ti ṣe nínú ìgò àyẹ̀wò, tí ó túmọ̀ sí pé wọ́n wo ipa tí ọ̀gbìn náà ní lára àwọn sẹ́ẹ̀lì àti àsopọ̀ ara kànkan, dípò nínú ara èèyàn gangan, Àwọn ìwádìí míràn ti sàyẹ̀wò ipa tí èso soursop ní lára eku àti ẹmó.

 Lára àwọn àyẹ̀wò yìí dàbí ẹnipé ó lè ní àṣeyorí. Àwọn ìwádìí àtẹ̀yìnwá fihàn pé ó ṣeéṣe kí àwọn ohun kan lára èso ọ̀hún wúlò láti dènà ààrùn jẹjẹrẹ tí ó ní ṣe pẹ̀lú òróǹró àti ọmú. Láìpẹ́ yìí, wọ́n fihàn pé èso soursop lè yan bí ó se ma dín ìdàgbàsókè sẹ́èlì jẹjẹrẹ kù. 

 Ní ọdún 2021 àgbéyẹ̀wò èsì ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwádìí fẹnukò pé èròjà èso soursop lè ní àwọn ǹkan tí ó lè nípa tí ó ṣeni lánfààní, léyìí tí dídènà ààrùn jẹjẹrẹ jẹ́ ọ̀kan lára rẹ̀. Ṣùgbọn gẹ́gẹ́ bí àwọn ìwádìí míràn, ara eku, ẹmó, àti sẹ́ẹ̀lì ènìyàn ni wọ́n ti ṣe èyí. Àwọn onímọ̀ sáyẹ́nsì ní ọ̀pọ̀ ìgbà ma ń rí èsì tí ó yàtò tí wọ́n bá ṣe ìwádìí náà lára èèyàn, nítorí náà irúfẹ́ àwọn ìwádìí yìí ni wọ́n kà sí ìwádìí kùtùkùtù tí kìí ṣe kònkárí.

 Ìwádìí lára èèyàn ṣọ̀wọ́n. Ìwádìí kan bèrè lọ́wọ́ àwọn tó ní ààrùn jẹjẹrẹ ọmú bóyá wọn jẹ èso soursop àti àwọn ewé àti egbò. Ó rí ìbáṣepò láàrín jíjẹ èso soursop àti díndín ìwọn yíye ààrùn nàà kù lẹ́yìn ọdún díẹ̀. Ṣùgbọ́n èyí kò túmọ̀ sí pé èso soursop ni ó dín ìwọ̀n yíye ààrùn náà kù. Ẹ jẹ́ ká ma rántí ní gbogbo ìgbà pe ìbáṣepọ̀ kò túmọ̀ sí okùnfà.

 Ìkìlọ̀ àti ìbániṣẹjọ́ lórí ọ̀rọ̀ tí kò lóòtọ́ nínú nípa èso soursop

Jíjẹ es̀o soursop jẹ́ ohun tí kò méwu dání rárá. “Kò wọ́pọ̀ pé ǹkan mímu tàbí oúnjẹ tí ó ní èso soursop lè ṣeni ní jàmbá tí èèyàn bá jẹ́ mọ̣́ àwọn oúnjẹ míràn,” gẹ́gẹ́ bí àjọ Cancer Research UK ṣe sọ. Ṣùgbọ́n àwọn dókítà ti kìlò pé jíjẹ èso náà lè ní àwọn ipa tó léwu lára àwọn ènìyàn kan bẹ́ẹ̀ sì ni ó lè dín iṣẹ́ àwọn ògùn ẹ̀jẹ̀ ríru àti àwọn àìsàn míràn kù. 

 Látàrí bí ó ṣe lókìkí tó ní ìṣègùn ìbílẹ̀, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àjọ oníṣègùn tí ó lórukọ ti ṣe ìkìlò nípa ọ̀gbìn ọ̀hún. Ní ọdún 2017, àjọ US Food and Drug Administration ṣe ìkìlò lóríṣiríṣi fún àwọn ilé iṣẹ́ mẹ́rìnlá tí ó ń sọ ọ̀rọ̀ tí kò lóòtó nínú nípa èso soursop àti àwọn ìtójú míràn fún ààrùn jẹjẹrẹ. 

Àwọn àjo míràn tí ó mọ̀ nípa ààrùn jẹjẹrẹ náà ti sọpé kò sí òótọ́ nínú àwọn ọ̀rọ̀ tí ó ń káàkiri nípa àìsàn yìí. Lára wọn ni Cancer Research UKCancer Treatment Centers of America àti Cancer Association of South Africa

 Bí ótilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìwádìí ti inú ìgò àyẹ̀wò àti àwọn eku àti ẹmó dàbí ẹnipé ó lè ní àṣeyorí nínú, kò sí ẹ̀rí pé èso soursop tàbí èròjà rè míràn lè wo ààrùn jẹjẹrẹ sàn ní ara èèyàn.

 

 

Republish our content for free

We believe that everyone needs the facts.

You can republish the text of this article free of charge, both online and in print. However, we ask that you pay attention to these simple guidelines. In a nutshell:

1. Do not include images, as in most cases we do not own the copyright.

2. Please do not edit the article.

3. Make sure you credit "Africa Check" in the byline and don't forget to mention that the article was originally published on africacheck.org.

For publishers: what to do if your post is rated false

A fact-checker has rated your Facebook or Instagram post as “false”, “altered”, “partly false” or “missing context”. This could have serious consequences. What do you do?

Click on our guide for the steps you should follow.

Publishers guide

Africa Check teams up with Facebook

Africa Check is a partner in Meta's third-party fact-checking programme to help stop the spread of false information on social media.

The content we rate as “false” will be downgraded on Facebook and Instagram. This means fewer people will see it.

You can also help identify false information on Facebook. This guide explains how.

Add new comment

Restricted HTML

  • Allowed HTML tags: <a href hreflang> <em> <strong> <cite> <blockquote cite> <code> <ul type> <ol start type> <li> <dl> <dt> <dd> <h2 id> <h3 id> <h4 id> <h5 id> <h6 id>
  • Lines and paragraphs break automatically.
  • Web page addresses and email addresses turn into links automatically.
limit: 600 characters

Want to keep reading our fact-checks?

We will never charge you for verified, reliable information. Help us keep it that way by supporting our work.

Become a newsletter subscriber

Support independent fact-checking in Africa.