Back to Africa Check

Kò sí ẹ̀rí pé agbẹnusọ ẹgbẹ́ òṣèlú APC tí ó wà lórí àléfà lọ́wọ́ lórílẹ̀dè Nàìjíríà ní èròngbà láti má fàyè gbà kí àwọn ará òkè ọya ó lo ẹ̀rọ ayélujára tàbí rẹ́díò lẹ́yìn ti ààrẹ télẹ̀rí gb

NÍ ÈDÈ KÚKÚRÚ: Ààrẹ orílẹ̀dè Nàìjíríà tẹ́lẹ̀rí tí ó lókìkí, ìyẹn Olusegun Obasanjo ti sàtìlẹyìn Peter Obi gẹ́gẹ́ bí olùdíje dupò ààrẹ tí ó nífe sí jùlọ nínú ètò ìdìbò tí ó ń bọ̀. Ní báyìí, ọ̀rọ̀ wọ́n pé kan tí kò lóòtọ́ nínú ń dáàbá pé ẹgbẹ́ òṣèlú APC tí ó ń ṣe ìjọba lọ́wọ́ kò fé kí àwọn tí ó wà ní igun agbára rẹ̀ ní apá àríwá ó lo àwọn ẹ̀rọ ìgbéìròyìnjáde, láti ri pé òkìkí Obi kò túbò kàn si. 

 

“Níbáyìí tí àtìlẹyìn fún Obi ti gbòde kan, a kò gbúdọ̀ gba àwọn èèyàn tí ó wà ní apá àríwá gangan láàyè láti lo ẹ̀rọ ayélujára àti rẹ́díò.” ọ̀rọ̀ wọ́n pé kan tí ó ń káàkiri orí Facebook ni ó kà báyìí

Festus Keyamo, agbẹnusọ fún ạ̀́jọ tí ó ń rísí ètò ìpolongo ààrẹ tí ó jẹ́ ti ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress (APC) tí ó ń ṣe ìjọba lọ́wọ́ lórílẹ̀dè Nàìjíríà ni wọ́n ní ó sọ béè.  

Peter Obi jẹ́ olùdíje dupò ààrẹ lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú Labour nínú ètò ìdìbò tí yíò wáyé lórílèdè ọ̀hún ní ọdún 2023, léyìí tí ma bẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ karùndínlógún oṣù kejì.

Ó jáde nínú ìròyìn pé olókìkí ààrẹ orílẹ̀dè Nàìjíríà tẹ́lẹ̀rí Olusegun Obasanjo ti yan Obi gẹ́gẹ́ bi olùdíje tí ó ní ìfẹ́ sí ní ọjọ́ kínní oṣù kínní. 

Àwọn olóṣèlú míràn ni ìròyìn sopé fọwọ́ sí ìpinnu Obasanjo. Ìfọwósí látọ̀dọ̀ ẹni tí ó gbajúmọ̀ báyìí ti fa oríṣiríṣi èsì látọ̀dọ̀ àwọn olùdíje dupò ààrẹ míràn àti àwọn ọmọlẹ́yìn wọn

Kókó ohun tí ọ̀rọ wọ́n pé yìí ń sọ nipé àìsí àǹfànní láti gbọ́ tàbí ka ìròyìn ní apá àríwá, tí ó jẹ́ igun agbára ẹgbẹ́ òṣèlú APC ni yíò fòpin sí bí Obi ṣe lè túbọ̀ gbajúmọ̀ si níbẹ̀ látàrí ìfọwọ́sí Obasanjo. 

Arí ọ̀rọ wọ́n pé náà lórí Facebook ní ibí àti ibí.  

Ṣùgbọ́n ṣé Keyamo sọpé ó yẹ kí wọ́n má gba àwọn ará òkè ọya láàyè láti lo ẹ̀rọ ayélujára tàbí rẹ́díò lẹ́yìn tí Obasanjo ṣàtìlẹyìn fún Obi? 

ObiQuote_False_

Kò sí ẹ̀rí fún ọ̀rọ̀ náà

Àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n gbé sórí Facebook náà kò sọ ibi tàbí ìgbà tí wọ́n ní pé Keyamo ti sọ ọ̀rọ̀ náà. Èléyìí jẹ́ àríṣá àwọn ọ̀rọ̀ tí kò lóòtọ́ nínú tí wọn ma ń gbé sórí òpó ìkànsíaraẹni.

A wá orí orúkọ ìdánimọ̀ Keyamo tí ó ní àmì àrídájú lórí Twitter fún ọ̀rọ̀ náà sùgbọ́n a kò rí èsì ọ̀rọ̀ tó jọ bẹ́ẹ̀. 

Àti pé kò jáde nínú ìròyìn látọwọ́ àwọn oníròyìn agbègbè. Ọ̀rọ̀ tí ó nípọn báyìí nípa pé wọn kò fẹ́ kí àwọn olùdìbò ó lo ẹ̀tọ́ wọn tí ó níṣe pẹ̀lú òṣèlú yíò ti jẹ́ àkólé ìròyìn

Africa Check láìpé yìí ti ṣe ìwádìí àwọn oríṣiríṣi ọ̀rọ̀ tí kò lóòtọ́ nínú tí wọ́n nípé àwọn olóṣèlú tí ó gbajúmọ̀ ló sọ bẹ́ẹ̀, e lè ri ní ibí, ibí, ibí, ibí àti ibí.

Bí ètò ìdìbò orílẹ̀dè Nàìjíríà ṣe ń súmó lé si, ka ìtọ́nisọ́nà wa lórí bí o ṣe lè mọ̀ tí ìròyìn kan bá jẹ́ òótó kí o má ba máa gba ìròyìn tí kò lóòtó nínú gbọ́. Bẹ́ẹ̀ sì ni ìtúsíwẹ́wẹ́ wa tàn mọ́lẹ̀ sí oríṣiríṣi àsà ìròyìn tí kò lóòtó nínú tí a máa ń rí ní àsìkò ìpolongo ìbò ní orílẹ̀dè Nàìjíríà.

 

Republish our content for free

We believe that everyone needs the facts.

You can republish the text of this article free of charge, both online and in print. However, we ask that you pay attention to these simple guidelines. In a nutshell:

1. Do not include images, as in most cases we do not own the copyright.

2. Please do not edit the article.

3. Make sure you credit "Africa Check" in the byline and don't forget to mention that the article was originally published on africacheck.org.

For publishers: what to do if your post is rated false

A fact-checker has rated your Facebook or Instagram post as “false”, “altered”, “partly false” or “missing context”. This could have serious consequences. What do you do?

Click on our guide for the steps you should follow.

Publishers guide

Africa Check teams up with Facebook

Africa Check is a partner in Meta's third-party fact-checking programme to help stop the spread of false information on social media.

The content we rate as “false” will be downgraded on Facebook and Instagram. This means fewer people will see it.

You can also help identify false information on Facebook. This guide explains how.

Add new comment

Restricted HTML

  • Allowed HTML tags: <a href hreflang> <em> <strong> <cite> <blockquote cite> <code> <ul type> <ol start type> <li> <dl> <dt> <dd> <h2 id> <h3 id> <h4 id> <h5 id> <h6 id>
  • Lines and paragraphs break automatically.
  • Web page addresses and email addresses turn into links automatically.
limit: 600 characters

Want to keep reading our fact-checks?

We will never charge you for verified, reliable information. Help us keep it that way by supporting our work.

Become a newsletter subscriber

Support independent fact-checking in Africa.