Back to Africa Check

Kò sí ẹ̀rí pé eré ìdárayá ìṣẹ̀jú mẹ́ẹ̀wá yìí lè mú kí pírósítétì tó wú ó súnkì ní kíá kíạ́̀́

NÍ ÈDÈ KÚKÚRÚ: Àtẹ̀ránṣẹ́ orí Facebook kan ni ó sọpé eré ìdárayá kan lè mú kí pírósítétì tó wú ó súnkì. Africa Check kò rí ẹ̀rí tó fìdí èyí múlẹ̀. 

 

Fídíò kan tí wọ́n gbé sórí Facebook ni ó sọpé ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹ̀rún ọkùnrin ni pírósítétì won tí ó wú ti súnkì láì lo ohunkóhun si, ṣùgbọ́n nípa ṣíṣe “eré ìdárayá ìṣẹ́jú-àáyá mẹ́wàá”.

Ní ìbẹ̀rẹ̀ fídíò ọ̀hún, tí wón tún tẹ̀ránṣẹ́ ní ibí yìí, ọkùnrin kan fẹ̀yìn lélè tí ó sì tẹ orókún rè, tí ó sorọ́bà yí itan rẹ̀ méjéèjì, tí ó sì ń ṣe eré ìdárayá tí ó ń ṣiṣẹ́ fún isan tí ó wà ní ìdí. 

Gẹ́gẹ́ bí fídíò náà ṣe fihàn, gbígbé ìbàdí sókè díèdíè kúrò ní ipò yìí, lè mú àwọn àmì àìlera bíi ìtọ̀ alẹ́, aìlè tọ ìtọ̀ tán tàbí ìtọ̀ tí kò jáde tààrà. 

Pírósítétì yìí wà láàrín okó àti àp̀o ìtọ̀. Pírósítétì tó wú ni a mọ̀ sí prostatic hyperplasia ní èdè gẹ̀ẹ́sì. 

Ṣùgbọ́n ṣe ́eré ìdárayá tí ó la òógùn lo yìí lè mú kí pírósítétì tó wú súnkì ní “kíá kíá” ? A sèwádìí 

ShrinkProstrate_False

Kíni Pírósítétì tó wú?

Gẹ́gẹ́ bí  webusite kan lórí ọ̀rọ̀ ìlera, WebMD ṣe sọ, pírósítétì wíwú jẹ́ èyí tó ń bá àwọn ọkùnrin tí ó ti lé ní àádọ́ta ọdún jà. Àwọn dókítà gbàgbọ́ pé àyípadà  hòmónù, bií ti dihydrotestosterone, hòmónù tí ó ń kópa nínú ìdàgbàsókè pírósítétì bá lọ sókè si ni ó lè sokùnfàá. 

Àwọn àmì pírósítétì wíwú jé kí èèyàn máa ní ìmọ̀lára láti tọ̀ ní gbogbo ìgbà, ìrora tí èèyàn bá ń tọ̀, tàbí àìlè tọ̀ ìtọ̀ tán. 

Cleveland clinic, ilé-iṣẹ́ ìṣègùn òyìnbó tí ó wà ní US sọpé kò sí ìwòsàn fún prostate wíwú. Ṣùgbọ́n wọ́n lè fi àwọn oògùn kan tí ó lè mú kí iṣan pírósítétì òhún silẹ̀, iṣẹ́ abẹ àti àwọn ọ̀nà míràn tí wọ́n gbà ṣe àtúnṣe nínú ara ní ìwọ̀mba, ṣíṣe àwọn àtúnṣe sí ìgbé ayé èni bíi yíyàgò fún ọtín mímu, àti àwọn ohun olómi míràn kí a tó sùn, lè dín àwọn àmì àìlera yìí kù. 

Kò sí ẹ̀rí láti fìdí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀ 

A rí àwọn àmì tó mú ìfunra dání nínú fídíò tí wọ́n gbé sórí Facebook. Àkọ́kọ́, ọkùnrin tí ó ń sọ̀rọ̀ nínú rẹ̀ kò sọ bí ó ṣe jẹ́ àti ǹkan tí ó jẹ́ kí ó kúnjúwọ̀n láti máa gba elòmíràn ní irú ìmòràn yìí. Àì lè sọ ní pàtó orísun ọ̀rọ̀ kan lórí òpò ìkànsíaraẹni ní ọ̀pọ̀ ìgbà jẹ́ àmì pé ìmọ̀ràn náà ò ṣe fọkàn tọ́. 

Ọkùnrin náà sọpé àwọn “oníwádìí Harvard” ti ṣèwádìí pé pírósítét̀i wíwú ṣe é “dápadà sí bí ó ṣe wà tẹ́lẹ̀”. A rí àkọsílẹ̀ ọdún 2022 kan tí Mathew Solan, olóòtú àgbà Harvard Men’s Health Watch kọ lórí bí wọ́n ṣe lè ṣe ìtọ́jú pírósítétì wíwú. Kò mẹ́nu ba eré ìdárayá tí ó ń ṣiṣẹ́ fún iṣan ìdí tàbí ọ̀nà tí wọn lè gbà “dapadà si bí ó ṣe wà tẹ́lẹ̀.”

A bá Johnson Udodi, alákòso ní Nigeria’s National Hospital Abuja, nípa ìlànà ìtọ́jú tí wọ́n mẹ́nu bà nínú fídíò yìí àti bóyá ó ń ṣiṣẹ́. 

Ó sọpé “Mi ò ní àlàyé kankan pé ìlànà ìdárayá yìí lè dá pírósítétì padà sí bí ó ṣe wà kí o tó wú”. Ó sọpé wọ́n ti ri pé ìbásepò wa láàrín ṣíṣe eré ìdárayá àti dídín ewu àkọlù pírósítétì wíwú kù, ṣùgbọ́n kò lè mú àmì àìlera yìí kúrò. 

Ademola Popoola, urologist àti olùkọ́ni àgbà ní yunifásitì Ilorin, sọfún Africa Check pé òhun kò lè sọ bóyá “eré ìdárayá yìí” lè wo àìsàn náà, 

“Eré ìdárayá kò lè wo pírósítétì wíwú tàbí kí ó dín bí ó ṣe tóbi tó kù tí wọ́n bá ti lè ridájú pé ṣe ni ó wú.”

Àwọn onímọ̀ méjèèjì fẹnu kò pé ohun tí ó yẹ ní ṣíṣe ni láti lo gba ìtọ́jú lọ́wọ́ àwọn tí ó kọ́ṣẹ́ mọṣẹ́ oògùn tí ó bá ní àmì kan tàbí púpọ̀ nínú àmì àìlera pírósítétì wíwú.

 

Republish our content for free

We believe that everyone needs the facts.

You can republish the text of this article free of charge, both online and in print. However, we ask that you pay attention to these simple guidelines. In a nutshell:

1. Do not include images, as in most cases we do not own the copyright.

2. Please do not edit the article.

3. Make sure you credit "Africa Check" in the byline and don't forget to mention that the article was originally published on africacheck.org.

For publishers: what to do if your post is rated false

A fact-checker has rated your Facebook or Instagram post as “false”, “altered”, “partly false” or “missing context”. This could have serious consequences. What do you do?

Click on our guide for the steps you should follow.

Publishers guide

Africa Check teams up with Facebook

Africa Check is a partner in Meta's third-party fact-checking programme to help stop the spread of false information on social media.

The content we rate as “false” will be downgraded on Facebook and Instagram. This means fewer people will see it.

You can also help identify false information on Facebook. This guide explains how.

Add new comment

Restricted HTML

  • Allowed HTML tags: <a href hreflang> <em> <strong> <cite> <blockquote cite> <code> <ul type> <ol start type> <li> <dl> <dt> <dd> <h2 id> <h3 id> <h4 id> <h5 id> <h6 id>
  • Lines and paragraphs break automatically.
  • Web page addresses and email addresses turn into links automatically.
limit: 600 characters

Want to keep reading our fact-checks?

We will never charge you for verified, reliable information. Help us keep it that way by supporting our work.

Become a newsletter subscriber

Support independent fact-checking in Africa.