Back to Africa Check

Kò sí ẹ̀rí pé olùdíje dupò ààrẹ lórílẹ̀dè Nàìjíríà Bola Tinubu sọpé òhun “pàdánù àwọn ọmọ kílàsì òhun ní ogun abélé ti Biafra”

NÍ ÈDÈ KÚKÚRÚ: Olùdíje lábẹ́ APC Bola Tinubu ni wọ́n ti dá lágara pẹ̀lú ìbéèrè nípa àwọn ìwé ẹri re, Ṣùgbọ́n àwọn ọ̀rọ̀ kan tí wọ́n sọpé òhun ló sọ kò ní ẹ̀rí kankan láti gbèé nídìí.

Ọ̀rọ̀ àgbàsọ kan tí ó ya ni lẹ́nu púpọ̀ tí wọ́n gbé sórí Facebook, ni wọ́n sọpé Bola Tinubu tí ó jẹ́ olùdíje lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú tí ó ń ṣè ìjọba lọ́wọ́lọ́wọ́ nínú ètò ìdìbò orílẹ̀dè Nàìjíríà ní ọdún tó ń bọ̀ ni ó sọbẹ́ẹ̀.

Pẹ̀lú ọ̀rọ̀ àgbàsọ yìí ni àwòrán Tinubu níbi tí ó ti ń bá àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀, ó kà báyìí: “Mo pàdánù gbogbo àwọn ọmọ kílàsì mi nínú ogun Biafra” ~~Asiwaju Bola Ahmed Tinubu.”

Bola Tinubu ń díje lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress nínú ètò ìdìbò tí yíò wáyé ní oṣù kejì ọdún 2023.

Ogun abélé orílẹ̀dè Nàìjíríà tí a tún mọ̀ sí ogun Nàìjíríà àti Biafra ni wọ́n jà láàrín ọdún 1967 sí 1970. Ó wáyé láàrín ìpínlẹ̀ kan ní apá gúúsù ìlà-oòrùn orílẹ̀dè Nàìjíríà tí ó fẹ́ yapa kúrò tí wọ́n pè ní Biafra àti ìjọba àpapọ̀ ti orílẹ̀dè Nàìjíríà, léyìí tí ó sokùnfa ikú ìṣirò mílíọ́nù kan ènìyàn.

Àwọn ìbéèrè nípa ipele tí Tinubu kẹ́kọ̀ọ́ dé àti àwọn ìwé-ẹ̀rí rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 1999 nígbà tí ó kọ́kọ́ gbápòtí fún ipò gómínà ní ìpínlẹ̀ Èkó.

Ìpinnu rẹ̀ láti díje dupò ààrẹ ní ọdún 2023 ni ó túbò fa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìbéèrè nípa ìtan bí ó ṣe kẹ́kọ̀ọ́, ọjọ́ orí rẹ̀, ẹni tí ó jẹ́ gangan àti ìlera rẹ̀. 

Festus Keyamo tí ó jẹ́ agbẹnusọ fún ìgbìmọ̀ ìpolongo APC nínú ìfọ̀rọ̀wérọ̀ lórí amóhùnmáwòrán gbìyànjú láti dahùn lára àwọn ìbéèrè wònyí lọ́nà tí kò finí gbérí mọ́, ṣùgbọ́n ó dà bí ẹnipé àwọn ìbéèrè wònyí ṣì pàpà ń jẹyọ síbẹ̀. 

A rí irú ọ̀rọ̀ àgbàsọ ọ̀hún lórí Facebook ní ibí, àti ibí.

TinubuQuote_False_2

Kò sí èrí ọ̀rọ̀ náà 

Àtẹ̀ránṣẹ́ orí Facebook òhún kò ṣe àlàyé ní kíkún nípa ìgbà àti ibi tí wọ́n ní Tinubu ti sọ ọ̀rọ̀ náà, Eléyìí jẹ́ àmì pé àtẹ̀ránṣẹ́ tí wọ́n gbé sórí òpó ìkànsíaraẹni jẹ́ irọ́.

A wá orí orúkọ ìdánimọ̀ Tinubu tí ó ní àmì àrídájú lórí Twiter àti ojú ìwé wẹ́ẹ̀bù rẹ̀ a kò rí ẹ̀rí ọ̀rọ̀ náà.

Àti pé, kò sí ìròyìn tí ó wá látọwọ́ àwọn oníròyìn ìbílè tí ó dántọ́, nípa ọ̀rọ̀ náà, léyìí tí ó yẹ kó wà tí ó bá jẹ́ pé òótó ni. 

Kò sí ẹ̀rí pé Tinubu sọpé gbogbo àwọn ọmọ kílàsì rẹ̀ ni ó kú nínú ogun abélé tí ó wáyé lórílẹ̀dè Nàìjíríà.

 

Republish our content for free

We believe that everyone needs the facts.

You can republish the text of this article free of charge, both online and in print. However, we ask that you pay attention to these simple guidelines. In a nutshell:

1. Do not include images, as in most cases we do not own the copyright.

2. Please do not edit the article.

3. Make sure you credit "Africa Check" in the byline and don't forget to mention that the article was originally published on africacheck.org.

For publishers: what to do if your post is rated false

A fact-checker has rated your Facebook or Instagram post as “false”, “altered”, “partly false” or “missing context”. This could have serious consequences. What do you do?

Click on our guide for the steps you should follow.

Publishers guide

Africa Check teams up with Facebook

Africa Check is a partner in Meta's third-party fact-checking programme to help stop the spread of false information on social media.

The content we rate as “false” will be downgraded on Facebook and Instagram. This means fewer people will see it.

You can also help identify false information on Facebook. This guide explains how.

Add new comment

Restricted HTML

  • Allowed HTML tags: <a href hreflang> <em> <strong> <cite> <blockquote cite> <code> <ul type> <ol start type> <li> <dl> <dt> <dd> <h2 id> <h3 id> <h4 id> <h5 id> <h6 id>
  • Lines and paragraphs break automatically.
  • Web page addresses and email addresses turn into links automatically.
limit: 600 characters

Want to keep reading our fact-checks?

We will never charge you for verified, reliable information. Help us keep it that way by supporting our work.

Become a newsletter subscriber

Support independent fact-checking in Africa.