Back to Africa Check

Olùdíje dupò ààrẹ orílẹ̀dè Nàìjíríà Tinubu ń wo olùfigagbága rẹ̀ Obi lórí amóhùnmáwòrán inú ọkọ̀ òfurufú? Rárá, ìlú mọ̀ọ́ká kan ni ó tẹ àwòrán tí wọ́n ti ṣarúmọjẹ sí ránṣẹ́

NÍ ÈDÈ KÚKÚRÚ: Nínú àwòrán kan tí a ti sarúmọjẹ sí, Bola Tinubu ti ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress ni ó ti dàbí enipé ó ń wo Peter Obi ti ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party lórí amóhùnmáwòrán tí ó wà nínú ọkọ̀ òfurufú, ṣùgbọ́n nínú àwòrán tí ó jẹ́ ojúlówó, ojú amóhùnmáwòrán ọ̀hún ṣófo.

Àwòrán kan tí a gbé sórí Facebook ni ó dàbí ẹnipé ó ń sàfihàn Bola Tinubu, olùdíje lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress ní ètò ìdìbò yíyan ààrẹ ti ọdún 2023 ní orílẹ̀dè Nàìjíríà, nínú ọkọ̀ ojú òfurufú pé ó ń wo olùfigagbága rẹ̀ Peter Obi lórí amóhùnmáwòrán. Obi jẹ́ olùdíje lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party.

Charles Oputa, tí ó jẹ́ olórin àti òsèré ni ó tẹ àwòrán ọ̀hún síta ní ọjọ́ kẹjo oṣù kẹwa ọdún 2022. Oputa ẹni tí àwọn ènìyàn mọ̀ sí Charly Boy, ní ẹ̀gbàrún lé ẹgbẹ̀dógún(13,000) omolẹ́yìn lórí Facebook

Àkọ́lé tí ó fi sí àwòrán ọ̀hún ni, “Káàbọ̀ sílé arákùnrin, ọkùnrin tí ó yẹ ní wíwò nìyí.”

Àwọn olùdìbò orílẹ̀dè Nàìjíríà ṣetán láti yan ààrẹ wọn tuntun ní ọjọ́ karùndínlọ́gbòn oṣù kejì ọdún 2023.

Ṣùgbọ́n ṣé àwòrán náà fihàn pé Tinubu ń wo Obi lórí amóhùnmáwòrán nínú ọkọ̀ ojú òfurufú?

TinubuObi_Fake

Tinubu ń wòta láti fèrèsé ọkọ̀ ojú òfurufú

Títọ pinpin àwòrán látèyìnwá lórí Google fihàn pé wọn ti sarúmọjẹ sí àwòrán náà.

Èsì ìwádìí fihàn wípé ìbèrè oṣù kẹwa ni wọ́n ya àwòrán òhún nígbà tí Tinubu padà sí orílẹ̀dè Nàìjíríà lẹ́yìn ìgbà tí ó rìnrìnàjò lọ sí ilẹ̀ UK. Aṣo kan náà ni ó wọ̀ nínú àwọn àwòrán yókù.

Nínú ojúlówó àwòrán náà, tí ẹgbẹ́ kan tí ó ń sàtìlẹyìn fún Tinubu gbé sórí Twitter ní ọjọ́ kẹfà oṣù kẹwa–ọjọ́ méjì kí Oputa tó gbé àwòrán sí orí Facebook– Tinubu ń wòta láti fèrèsé ọkọ̀ òfurufú. Ojú amóhùnmáwòrán tí ó wà níwájú rẹ̀ ṣófo.

Nínú Ìròyìn kan nípa dídé padà rẹ̀ sí orílẹ̀dẹ̀ Nàìjíríà ní àwòrán tí ó jẹ́ ojúlówó yìí àti àwọn míràn tíwọ́n yà níbí ayẹyẹ tí wọ́n ṣe láti ki káàbọ̀. 

 

Republish our content for free

Please complete this form to receive the HTML sharing code.

For publishers: what to do if your post is rated false

A fact-checker has rated your Facebook or Instagram post as “false”, “altered”, “partly false” or “missing context”. This could have serious consequences. What do you do?

Click on our guide for the steps you should follow.

Publishers guide

Africa Check teams up with Facebook

Africa Check is a partner in Meta's third-party fact-checking programme to help stop the spread of false information on social media.

The content we rate as “false” will be downgraded on Facebook and Instagram. This means fewer people will see it.

You can also help identify false information on Facebook. This guide explains how.

Add new comment

Restricted HTML

  • Allowed HTML tags: <a href hreflang> <em> <strong> <cite> <blockquote cite> <code> <ul type> <ol start type> <li> <dl> <dt> <dd> <h2 id> <h3 id> <h4 id> <h5 id> <h6 id>
  • Lines and paragraphs break automatically.
  • Web page addresses and email addresses turn into links automatically.
limit: 600 characters

Want to keep reading our fact-checks?

We will never charge you for verified, reliable information. Help us keep it that way by supporting our work.

Become a newsletter subscriber

Support independent fact-checking in Africa.