Back to Africa Check

Rárá, ààrẹ orílẹ̀dè Nàìjíríà tẹ́lẹ̀rí Obasanjo kò fọwọ́sí Tinubu, olùdíje lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú tí ó ń ṣèjọba lọ́wọ́ lórílẹ̀dè Nàìjíríà fún ipò ààrẹ

NÍ ÈDÈ KÚKÚRÚ: Nínú àtẹ̀jáde kan tí ó ń kákìri lórí àwọn òpó ìkànsíaraẹni ni orílẹ̀dè Nàìjíríà, ó dàbí pé ààrẹ orílẹ̀dè Nàìjíríà télèrí Olusegun Obasanjo fọwọ́sí kí olùdíje dupò ààrẹ lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC Bola Tinubu di ààrẹ. Sùgbọ́n kìí ṣe òótọ́ ni ó so ọ̀rọ̀ tí wọ́n tẹ̀ yìí, òfútùfẹ́ẹ̀tẹ̀ s̀i ni ìfọwọ́sí ọ̀hún.

Síkírínsọọ̀tì kan tí ó ń káàkiri lóri Facebook léyìí tí ó ní ọ̀rọ̀ kan tí ó dàbí ẹnipé ó ti ẹnu ààrẹ ẹ̀ méjì lórílẹ̀dè Nàìjíríà Olusegun Obasanjo, fọwọ́sí  kí Bola Tinubu ó jẹ ààrẹ tí ó kàn lórílẹ̀dè Nàìjíríà.

Tinubu jẹ gómínà tẹ́lẹ̀rí ní ìpínlẹ̀ Èkó tí ó wà ní apá Gúúsù-ìwọ̀-oòrùn orílẹ̀dè Nàìjíríà àti olùdíje lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú tí ó wà níjọba lọ́wọ́, All Progressives Congress.

Ọ̀rọ̀ tí ó tẹnu jáde tí ó wà nínú Síkírínsoọ̀tì ọ̀hún, léyìí tí ó ní àwòrán Obasanjo àti Tinubu nínú kà báyìí: “ Èmi kìí ṣe olóṣèlú, ológun tí a ṣe ní ọ̀ṣọ́ ni mí, ọ̀gágun ni mí. Tí e bá ń wá olóṣèlú tí ó kúnjúwọ̀n ẹ lọ sí Èkó ní Bourdillon, e máa níbẹ̀.” 

Tinubu ń gbé ní ọ̀nà Bourdillon tí ó wà ní Ikoyi, ní ìpínlẹ̀ Èkó, léyìí tí ó jẹ́ agbègbè tí àwọn ọlọ́rọ̀ ń gbé

Lẹ́yìn tí ó dàbí ẹnipé ó sọpé “ó kù díè kí òhún da ìjọba àti ìpínlẹ̀ [Bola] rú” wọ́n nípé Obasanjo sọpé Tinubu “yè nítorí pé ó ní ọ̀pá tí ó fi ń pidọ́n lọ́wọ́. Mo sì lérò wípé yíò ní ànfààní láti lo ọ̀pá tó fi ń pidọ́n yìí káàkiri orílẹ̀dè Nàìjíríà.

Obasanjo sin orílẹ̀dè Nàìjíríà gẹ́gẹ́ bi adarí ìjọba ológun láàrín ọdún 1976 àti 1979 tí ó sì jẹ́ ààrẹ orílẹ̀dè Nàìjíríà láàrín ọdún 1999 sí 2007, Ó darí ẹgbẹ́ òsèlú People’s Democratic Party.

Síkírínsọọ̀tì tí wọ́n fi léde ní ọjọ́ keje oṣù kẹwa ọdún 2022, ni wọ́n tẹ̀ jáde ní ibí àti ibí

Ṣùgbọ́n, ṣé Obasanjo ṣàpèjúwe Tinubu gẹ́gẹ́ bíi “olóṣèlú tí ó kúnjúwọ̀n” tí ó ní “ọ̀pá tí ó fi ń pidọ́n” lọ́wọ́?

Obasanjo_False 2

Obasanjo: ‘Irọ́ àti èké ni’

Obasanjo ti sọ wípé òhun kò fọwọ́sí Tinubu nínú ọ̀rọ̀ tí ó fi léde tí agbẹnusọ ààrẹ orílẹ̀dè Nàìjíríà tẹ́lẹ̀rí náà, Kehinde Akinyemi bọwọ́ lù.

Nínú ọ̀rọ̀ tí wọ́n tẹ̀ síta tí wọ́n fi ṣọwọ́ sí Africa Check, Obasanjo sọpé: Ológun nìkan ni ó máa ń kó àwọn ènìyàn bí wọn ṣe lè jẹ́ adarí rere yálà fún ènìyàn tàbí àwọn ohun èlò. Nítorí náà èmi kò lè fẹnu tẹ́mbẹ́lú òṣèlú tí ó jẹ iṣé ọlọ́lá tí kò ní ìlànà ìdánilẹ́kọ tó lágbara. Èyí jẹ́ irọ́ àti èké. 

Àwọn ilé-iṣé oníròyìn ti gbé àtẹ̀jáde ọ̀hún náà, tí ó ń bẹnu àtẹ́ lu ọ̀rọ̀ wípé Obasanjo fọwọ́sí kí Tinubu ó di ààrẹ orílẹ̀dè Nàìjíríà. Irọ́ ni. 

 

Republish our content for free

We believe that everyone needs the facts.

You can republish the text of this article free of charge, both online and in print. However, we ask that you pay attention to these simple guidelines. In a nutshell:

1. Do not include images, as in most cases we do not own the copyright.

2. Please do not edit the article.

3. Make sure you credit "Africa Check" in the byline and don't forget to mention that the article was originally published on africacheck.org.

For publishers: what to do if your post is rated false

A fact-checker has rated your Facebook or Instagram post as “false”, “altered”, “partly false” or “missing context”. This could have serious consequences. What do you do?

Click on our guide for the steps you should follow.

Publishers guide

Africa Check teams up with Facebook

Africa Check is a partner in Meta's third-party fact-checking programme to help stop the spread of false information on social media.

The content we rate as “false” will be downgraded on Facebook and Instagram. This means fewer people will see it.

You can also help identify false information on Facebook. This guide explains how.

Add new comment

Restricted HTML

  • Allowed HTML tags: <a href hreflang> <em> <strong> <cite> <blockquote cite> <code> <ul type> <ol start type> <li> <dl> <dt> <dd> <h2 id> <h3 id> <h4 id> <h5 id> <h6 id>
  • Lines and paragraphs break automatically.
  • Web page addresses and email addresses turn into links automatically.
limit: 600 characters

Want to keep reading our fact-checks?

We will never charge you for verified, reliable information. Help us keep it that way by supporting our work.

Become a newsletter subscriber

Support independent fact-checking in Africa.