Ìfiránṣẹ́ kan tí a gbé sórí Facebook ní orílẹ̀dè Nàìjíríà sọpé ajo Federal Inland Revenue Service, tàbí Firs, ń ṣe ètò ìgbanisíṣẹ́ fún ọdún 2022-23.
It reads: “FIRS has commenced 2022/2023 Recruitment process. This article explains the required guidelines that will enhance your chances of being enlisted in this year’s Federal Inland Revenue Service Recruitment exercise.”
O ka bayii: “FIRS ti bẹ̀rẹ̀ ètò ìgbanisíṣẹ́ ti ọdún 2022/2023. Àkọsílẹ̀ yìí yíò sàlàyé àwọn ìlànà tí ó yẹ tí ó lè jẹ́ kí ó rọrùn fún ọ láti forúkọ sílẹ̀ fún ètò ìgbanisíṣẹ́ ti Federal Inland Revenue Service ti ọdún yìí.”
Ó tún fi link, tí ó sèlérí pé “ ọ̀rọ̀ ní kíkún bí o ṣe lè forúkọsílẹ̀”. A rí irú àtẹ̀ránṣẹ́ yìí, tí ó ní link lọ oríṣiríṣi webusite, níbí àti ibí.
Iṣẹ́ Firs ni láti ṣe àgbéyèwò, gbígba àti ìṣirò owó-orí àti àwọn owó míràn tí ó ń wọlé fún orílẹ̀dè Nàìjíríà, ọrọ̀ ajé tí ó tobi jùlọ nilẹ̀ adúláwọ̀. Sùgbọ́n ṣé wọ́n gbani sísẹ́?

Wọn kò gbanisíṣé ní àjọ tí ó ń gbowó-orí
Kò sí ẹ̀rí ìgbanisíṣẹ́ lórí webusite Firs, orúkọ ìdánimọ̀ rẹ̀ lórí Twitter, àbí Facebook.
Ní ọjọ́ kínní oṣù kẹ́jọ ọdún 2022 Firs tẹ gbólóhùn síta lórí orúko ìdánimọ̀ rẹ̀ lórí Twitter àti Facebook, tí wọ́n ṣe ìkìlọ̀ kí àwọn èèyàn ó kíyèsára fún àwọn oníjìbìtì wọ́n sì tún sọpé wọn kò gbanisíṣẹ́.
‘Àjọ yìí fẹ́ sọ pèlú ìdánilójú wípé kò ṣètò ìgbanisíṣẹ́ kankan lọ́wọ́lọ́wọ́ àti ní pàtàkì pé kìí ṣe ètò ìgbani síṣẹ́ ní ọ̀nà ayédèrú,” gbólóhùn náà kà báyìí.
Ó ṣe ìkìlò fún àwọn oníròyìn láti má gbé ìròyìn ètò ìgbanisíṣẹ́ èké tàbí èyí tí wọn kò fọwọ́ sí síta.
Republish our content for free
For publishers: what to do if your post is rated false
A fact-checker has rated your Facebook or Instagram post as “false”, “altered”, “partly false” or “missing context”. This could have serious consequences. What do you do?
Click on our guide for the steps you should follow.
Publishers guideAfrica Check teams up with Facebook
Africa Check is a partner in Meta's third-party fact-checking programme to help stop the spread of false information on social media.
The content we rate as “false” will be downgraded on Facebook and Instagram. This means fewer people will see it.
You can also help identify false information on Facebook. This guide explains how.
Add new comment