Ìfiránṣẹ́ kan tí ó ń káàkiri lóri Facebook sopé àjọ Immigration ti orílẹ̀dè Nàìjíríà ti bẹ̀rẹ̀ ètò ìgbanisíṣẹ́ ti ọdún 2022.
“Ètò ìgbanisíṣẹ́ ti Immigration ti ọdún 2022–Èyí ni láti fi tó yín létí wípé NIS ti bẹ̀rẹ̀ ètò ìgbanisíṣẹ́ fún ọdún 2022. Ẹ lọ wo ojú ìwé wẹ́ẹ̀bù ìgbanisíṣẹ́ àjọ Immigration orílẹ̀dè Nàìjíríà,” ó kà báyìí. Ó fi link tí ó lọ wẹbusite níbi tí ó ní pé àwọn èèyàn lè forúkọ sílẹ̀.
Ìfiránṣẹ́ míràn sọfún àwọn ọ̀dọ́ kí wọ̣́n “pé Adetunji Adebayo lórí 08062549981” láti lè gba ẹyọ̀kan lára iṣẹ́ mẹ́ẹ̀wá tí ó wà fún àwọn ọ̀dọ́ ní àjọ òhún.
Ǹjé òótọ́ ni àwọn iṣẹ́ yìí? A ṣe ìwádìí.

‘Iṣẹ́ ọwọ́ àwọn oníjìbìtì èèyàn’
Link tí ó wà nínú àwọn ìfiránṣẹ́ ọ̀hún lọ sí ojú ìwé wẹ́ẹ̀bù lóri wẹbusite tí orúkọ rè ń je Celebidentity. Ọgbọ̀n ọjọ́ oṣù kẹfà ọdún 2022 ni ó wà lórí ojú ìwé wẹ́ẹ̀bù náà àtipé ó sọpé ìforúkọ sílẹ̀ fún iṣẹ́ ní àjọ immigration yíò wá sópin ní ọjọ́ kọkànlélọ́gbọ̀n oṣù keje. Ó polówó àwọn ipò míràn náà.
Ní ọjọ́ kínní oṣù keje, ni àjọ Immigration ti orílẹ̀dè Nàìjíríà tẹ gbólóhùn síta lórí Facebook tí ó ṇ kìlò pé àwọn iṣẹ́ tí wọ́n polówó kìí ṣe látọwọ́ wọn bẹ́ẹ̀ sìni ó jẹ́ ọ̀nà láti lu àwọn èèyàn ní jìbìtì. Àkọ̀rí rẹ̀ jẹ́: “Ẹ ṢỌ́RA FÚN ÀWỌN ONÍṢÉ JÌBÌTÌ: A KÒ GBANISÍṢÉ.”
“A ti pe àkíyèsí aṣojú ọ̀gá àgbà pátápátá ti àjọ Immigration Isah jere Idris sí àwọn ìpolówó kan tí ó ń káàkiri látowo àwọn tí ó ń gbé ìròyìn jáde tí wọ́n kéde ètò ìgbanisíṣẹ́/ìfirọ́pò ní àjọ immigration,” gbólóhùn náà kà.
“Ó ṣe pàtàkì láti sọ ní pàtó pé ìpolówó yìí jẹ iṣẹ́ àwọn oníjìbìtì èèyàn kan tí ó ń wọ́nà láti tan àwọn èèyàn jẹ àti láti lu àwọn ará ìlú ní jìbìtì àwọn ohun ìní wọn tí wọ́n ṣiṣé kára kára fún lóri iṣẹ́ tí kò sí.”
Republish our content for free
For publishers: what to do if your post is rated false
A fact-checker has rated your Facebook or Instagram post as “false”, “altered”, “partly false” or “missing context”. This could have serious consequences. What do you do?
Click on our guide for the steps you should follow.
Publishers guideAfrica Check teams up with Facebook
Africa Check is a partner in Meta's third-party fact-checking programme to help stop the spread of false information on social media.
The content we rate as “false” will be downgraded on Facebook and Instagram. This means fewer people will see it.
You can also help identify false information on Facebook. This guide explains how.
Add new comment