Back to Africa Check

Rárá bàlúù kò já lulẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Èkó, Wọn ń gbé bàlúù ti orílẹ̀dè Nàìjíríà kan tí wọ́n tà lọ síbò míràn ni

 

Fídíò ọkọ̀ ojú òfurufú kan tí kò ní ìyẹ́ mọ́ tí wọ́n ń gbé lọ ní òpópónà márosẹ̀ kan ni ó ń káàkiri ní orílẹ̀dè Nàìjíríà, tí àwọn kan sì ń sopé ṣe ni ọkọ̀ ojú òfurufú náà já lulẹ̀ ní pópónà kan tí ó súnmọ́ pápá ọkọ̀ òfurufú ti Murtala Muhammed ní ìlú Ikeja ní ìpínlẹ̀ Èkó.

Àwọn ońiròyìn ti agbègbè díẹ̀ náà gbé ìròyìn yìí ní àsìkò tí ó ku díẹ̀ kí osù káàrún, ọdún 2022 ó parí.

Ṣùgbọ́n kíni ìròyìn náà lẹ́kùnrẹ́rẹ́

crash-land

Àwọn aláṣẹ bẹnu àtẹ́ lu ìròyìn ọ̀hún

Federal Airports Authority of Nigeria (FAAN), ilé-iṣé ìjọba tí ó jẹ́ alákóso àwọn pápá ọkọ̀ ojú òfurufú tí ó ń powó wọlé bẹnu àtẹ́ lu ọ̀rọ̀ náà.

FAAN nínú ọ̀rọ̀ tí wọ́n gbé sóri Facebook ní ọjó kerìnlélógún, oṣù káàrún so fún àwọn ará ìlú wípé “ẹ má gba ìròyìn tí ó ń káàkiri lórí àwọn òpó ìkànsíaraẹni nípa ọkọ̀ ojú òfurufú tí ó já lulẹ̀ ní pápá ọkọ̀ ojú òfurufú Ikeja gbọ́. Ẹni tí ó ni ọkọ̀ ojú òfurufú ọ̀hún ti tàá fún oníbàrà, tí ó ń gbe lọ sí ibi tirẹ̀.”

Lagos State Emergency Agency náà bẹnu àtẹ́ lu ìròyìn náà, wọ́n sọpé “Ǹkan tí ó jọ béè kò sẹlẹ̀”, gẹ́gẹ́ bí ìwé-ìròyìn Punch ti gbe síta.

Kò sí àmì ìjàmbá lára ọkọ̀ ojú òfurufú náà

Ọkọ̀ ojú òfurufú tí ó wà nínú fídíò náà kò ní àmì ìjàmbá kànkan lára, bẹ́ẹ̀ sìni ó hàn wípé ṣe ni wọ́n yọ ìyẹ́ rẹ̀ bí ó ṣe yẹ kí wọ́n yọ́.

Nínú àwọn àsopọ̀ tweet, amòye nípa iṣẹ́ ọkọ̀ òfurufú Daniel Dikio nípé bàlúù náà jẹ́ Airbus A319, àti pé wọ́n ti yọ ìyẹ́ rẹ̀ sọ́tọ̀ bó ṣe tọ́.

“Eléyìí kò le è sẹlẹ̀ nínú ìjàmbá, Ìyọsọ́tọ̀ yìí jẹ́ àmì wípé wọn tú ba lẹ̀ ni. Kò sí ìbàjẹ̀ kànkan lára bàlúù náà, léyìí tí kò ní ṣaláì wáyé tí ọ̀rọ̀ bá rí bí wọ́n ṣe sọ.”

Mo ti sàtúnyẹ̀wò data súnkẹrẹ-fàkẹrẹ ojú òfurufú mi ò sì rí ǹkan tí ó sàjèjì, àti wípé gbogbo àwọn bàlúù A320 tí ó ń ṣiṣẹ́ lọ́wọ́ ní orílèdè Nàìjíríà ni ó pé níye lẹ́yìn tí mo kà wọ́n,” tweet Dikio ló kà báyìí.

 

Republish our content for free

We believe that everyone needs the facts.

You can republish the text of this article free of charge, both online and in print. However, we ask that you pay attention to these simple guidelines. In a nutshell:

1. Do not include images, as in most cases we do not own the copyright.

2. Please do not edit the article.

3. Make sure you credit "Africa Check" in the byline and don't forget to mention that the article was originally published on africacheck.org.

For publishers: what to do if your post is rated false

A fact-checker has rated your Facebook or Instagram post as “false”, “altered”, “partly false” or “missing context”. This could have serious consequences. What do you do?

Click on our guide for the steps you should follow.

Publishers guide

Africa Check teams up with Facebook

Africa Check is a partner in Meta's third-party fact-checking programme to help stop the spread of false information on social media.

The content we rate as “false” will be downgraded on Facebook and Instagram. This means fewer people will see it.

You can also help identify false information on Facebook. This guide explains how.

Add new comment

Restricted HTML

  • Allowed HTML tags: <a href hreflang> <em> <strong> <cite> <blockquote cite> <code> <ul type> <ol start type> <li> <dl> <dt> <dd> <h2 id> <h3 id> <h4 id> <h5 id> <h6 id>
  • Lines and paragraphs break automatically.
  • Web page addresses and email addresses turn into links automatically.
limit: 600 characters

Want to keep reading our fact-checks?

We will never charge you for verified, reliable information. Help us keep it that way by supporting our work.

Become a newsletter subscriber

Support independent fact-checking in Africa.