NÍ ÈDÈ KÚKÚRÚ: Ọ̀rọ̀ àhésọ kan tí ó ń káàkiri ní àárín oṣù kẹwa ọdún 2023 pé ògágun àti adarí orílẹ̀dè Nàìjíríà tẹ́lẹ̀rí Yakubu Gowon ti kú, ni a ṣèwádìí pé irọ́ ni.
Ògágun tí ó jẹ́ adarí oríllẹ̀dè Nàìjíríà tẹ́lẹ̀rí Yakubu Gowon ti kú, lẹ́ni ọmọ ọdún mókàndínlàádòrún” báyìí ni àtẹ̀ránṣẹ́ kan lórí Facebook kà.
Àtẹ̀ránṣẹ ọjọ́ kẹsan oṣù kẹwa ọdún 2023 òhún ni ó sọpé ògagún àti adarí orílẹ̀dè Nàìjíríà tẹ́lẹ̀rí tó sì jẹ ajagun fẹ̀yìntì ti kú lọmọ ọdún mọ́kàndínlàádòrún.
Àtẹ̀ránṣé náà ni ó lé ní ọgọrun èèyàn ti nífẹsi tí wọn sì dási, tí oríṣiríṣi ìmọ̀lára àwọn aṣàmúlò Facebook sì pẹ̀lú rẹ̀. Ṣùgbọ́n ṣé òótọ́ ni?
Gowon ò kú!
Ìpínlẹ̀ Plateau ni wọ́n bí Yakubu Gowon sí ní ọdún 1934. Ó kàwé ní ibi tí à mọ̀ sí ìpińlẹ̀ Kaduna ní ìsinyìí tí ó sì bẹ̀rẹ̀ iṣé rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ológun.
Gowon jẹ́ adarí ìjọba ológun láàrín ọdún 1966 sí ọdún 1975.
Adeyeye Ajayi, Olùrànlọ́wọ́ sí Gowon fún ra rẹ̀, ni ó já irọ́ pé ọ̀gágun tẹ́lẹ̀rí òhún ti papòdà.
Ìwé ìròyìn The Cable gbé ọ̀rọ̀ látẹnu Gowon síta bí ó ṣe sọ pé “ Mo ṣì wà láyé àti ní àláfíà. Mi ò kánjú” nínú àtẹ̀jáde tí o fi ránṣẹ́ sí Nigerian Television Authority.
Nínú ìròyìn tí Punch tẹ̀ síta, Olorogun Kenneth Gbagi, Mínísítà tẹ́lẹ̀rí fún ìpínlè lórí ètò ẹ̀kó, sàpèjúwe àhésọ tí ó ń káàkiri ọ̀hún gẹ́gẹ́ bí “Iṣé ọwọ́ àwọn elérò búburú.”
Àhésọ pé Gowon ti kú kìí ṣe òótọ́.
For publishers: what to do if your post is rated false
A fact-checker has rated your Facebook or Instagram post as “false”, “altered”, “partly false” or “missing context”. This could have serious consequences. What do you do?
Click on our guide for the steps you should follow.
Publishers guideAfrica Check teams up with Facebook
Africa Check is a partner in Meta's third-party fact-checking programme to help stop the spread of false information on social media.
The content we rate as “false” will be downgraded on Facebook and Instagram. This means fewer people will see it.
You can also help identify false information on Facebook. This guide explains how.
Add new comment