Back to Africa Check

Rárá, omi látara ewé kókò kò lè ṣe ìtójú ìdí yíyọ

Àtẹránsẹ́ kan lórí Facebook ní orílèdè Nàìjíríà nípé “agbára ìwòsàn” “omi latara” ewéko lè ṣe ìtọ́jú ìdí yíyọ.

Lábẹ́ àkọ̣̀rí “Ṣise itoju idi yiyo” o kaa bayii: “Lo agbára ìwòsàn tí ó wà nínú omi látara kókò tí màá sọ fún ọ. Omi látara rẹ̀ máa ń siṣẹ́ fún ìdí yíyọ (Hemorrhoids ní èdè gẹ̀ẹ́sì), Akọ jẹ̀dí (ní èdè Yorùbá).”̀

Kókò tí a tún mọ̀ sí taro jẹ́ ǹkan ọ̀gbìn oụ́njẹ tí wọ́n máa ń gbìn ní ọ̀pọ̀ ìgbà nítorí gbòngbò rẹ̀, bí ó ti lẹ̀ jẹ́ pé gbogbo ara rẹ̀ ni ó ṣe ń jẹ.

Àtẹ̀ránṣé náà sàpèjúwe bí a ṣe lè gé ewé kókò àti bí a ṣe lè fi sí ìdí yíyo tí ó sì tún so wípé “omi látara ewé náà yio mú kí ìdí yíyọ náà wọlé padà. A ti danwò ó ṣe ń gbékèlé”.

Ṣé omi látara kókò lè ṣe ìtọ́jú ìdí yíyọ? A ṣe ìwádìí.

Cocoyam_false

Okùnfà ni yio júwe irú ìtọ́jú tí wọ́n lè fun

Ìdí yíyọ tí a mọ̀ sí piles ní èdè gẹ̀ẹ́sì ni tí iṣon tí ó wà ní ẹnu ìfun ńlá àti àyíká ihò ìdí, léyìí tí ó lè wà nínú tàbí ní ìta.  

Àwọn àmì ìdí yíyọ ni ìrora tàbí ìnira ní ibẹ, tí ó bá wú, tí ó bá ń ṣèjẹ̀ àti tí ìdí bá ń yọ.

A bèèrè lọ́wọ́ Dókítà Joanah Ikobah, tí ó jẹ́ consultant paediatric gastroenterologist àti hepatologist àti olùkọ́ àgbà ní yunifaásitì ìlú Calabar ní gúúsù orílẹ̀dè Nàìjíríà nípa ṣíṣe ìtọ́jú pẹ̀lú kókò

“Omi látara kókò kìí ṣe ìtọ́jú fún ìdí yíyọ. Ní àkọ́kọ́ a ní láti mọ ohun tí ó ń ṣokùnfà ìdí yíyọ ọ̀hún, ǹkan bíi àìrígbẹ́yà déédé. [àìlera náà] ṣe ń tọ́jú pẹ̀lú oògùn irú èyí tí wọ́n lè kì wo inú iho idi, tí ó bá pọ̀ gan a lè ṣe iṣé abẹ,” ó sọfún wa.

Ikobah nípé ọ̀pọ̀ ìgbà, okùnfà àti bí ìdí yíyọ náà bá ṣe le tó ni yio sọ bí wọ́n yio ṣe ṣè ìtọjú rẹ̀.

Gẹ́gẹ́ bí National Health Service ti ilẹ̀ UK ṣe sọ, a lè dènà tàbí ṣe ìtọ́jú ìdí yíyọ nípa mímu omi púpọ̀, jẹ oúnjẹ tí ó lè jẹ́kí a rí ìgbẹ́ yà dédé, wíwẹ̀ pẹ̀lú omi tí ó lọ́ wórọ́ tí ó lè dín ìrora tàbí yíyún kù, ṣíṣe eré ìdárayá dédé, kí a dín otín mímu àti caffeine kù.

Africa Check ti ṣe ìwádìí tí ó fihàn wípé àwọn wọ́nípé kan nípa lílo àpòpọ̀ lóríṣiríṣi láti ṣe ìtọ́jú ìdí yíyọ jẹ́ òfútùfẹ́ètẹ̀. 

 

For publishers: what to do if your post is rated false

A fact-checker has rated your Facebook or Instagram post as “false”, “altered”, “partly false” or “missing context”. This could have serious consequences. What do you do?

Click on our guide for the steps you should follow.

Publishers guide

Africa Check teams up with Facebook

Africa Check is a partner in Meta's third-party fact-checking programme to help stop the spread of false information on social media.

The content we rate as “false” will be downgraded on Facebook and Instagram. This means fewer people will see it.

You can also help identify false information on Facebook. This guide explains how.

Further Reading

Add new comment

Restricted HTML

  • Allowed HTML tags: <a href hreflang> <em> <strong> <cite> <blockquote cite> <code> <ul type> <ol start type> <li> <dl> <dt> <dd> <h2 id> <h3 id> <h4 id> <h5 id> <h6 id>
  • Lines and paragraphs break automatically.
  • Web page addresses and email addresses turn into links automatically.
limit: 600 characters

Want to keep reading our fact-checks?

We will never charge you for verified, reliable information. Help us keep it that way by supporting our work.

Become a newsletter subscriber

Support independent fact-checking in Africa.