Back to Africa Check

Rárá, yíyọ ikùn ní ìdá àádòrún ìgbà kìí ṣe àmì àìsàn ẹ̀dọ̀- a gbọ́dọ̀ ṣe àyẹ̀wò tó mọ́yán lórí

“Àmì àkọ́kọ́ wípé ẹ̀dọ̀ ní ọ̀rá púpọ̀ tàbí àìsàn ẹ̀dọ̀ míràn ni yíyọ ikùn,” àtẹ̀ránṣẹ́ kan tí ó ní àṣìko nínú tí wọ́n gbé sóri Facebook ní orílẹ̀dè Nàìjíríà ló kà báyìí. Léyìí tí ó n sọ̀rọ̀ nípa yíyọ ikùn.

Ikùn yíyọ ní èdè kúkúrú ni tí ikùn bá ṣe roboto. Sùgbọ́n àtẹ̀ránsẹ́ òhún sọpé àwọn ènìyàn tí ó bá yọkùn ní ìgbà ìdá àádọ́rùn ni ó lè wà nínú ewu àìsàn ẹ̀dọ̀ ọlọ́ọ̀rá púpọ̀ tàbí àìsàn ẹ̀dọ̀ míràn.

“lọ́gán tí o bá ti yọkùn, ànfààní wípé ẹ̀dọ̀ rẹ lè ní ọ̀rá púpọ̀ tó ìdá àádòrún,” àtẹ̀ránsẹ́ náà kà báyìí.

 Ǹjẹ́ àwọn ènìyàn tí ó yọkùn ní ìdá àádó̀rún ìgbà lè ní àìsàn ẹ̀dọ̀ ọlọ́ọ̀rá púpọ̀? A ṣe ìwádìí.

fatty liver

Ṣíṣe àyẹ̀wò ni ó lè sọ tí ó bá jẹ́ àìsàn ẹ̀dọ̀

Àìsàn ẹ̀dọ̀ ọlọ́òrá púpọ̀ ni tí ọ̀rá bá kórajọpọ̀ sínú ẹ̀dọ̀, léyìí tí ó jẹ́ ẹ̀yà ara tí ó tóbi jùlọ nínú ara wa. (Àwọ̀ ni èyà ara tí ó tóbi jù lọ, sùgbọ́n tó wà níta). Ẹ̀dọ̀ wà ní iwájú ara wa, lábẹ́ ẹ̀dọ̀fóró wa tí ó wà ní orí́ ikùn wa. Ohun tí à ń pè ní inú wà ní ìsàlẹ̀ ẹ̀dọ̀ àti ikùn.

Àìsàn ẹ̀dọ̀ ọlọ́òrá púpọ̀ tí kò ní ṣe pẹ̀lú ọtín àmupara ni à ń pè ní non-alcoholic fatty liver disease. Alcoholic fatty liver disease, gẹ́gẹ́ bí orúkọ rẹ̀ ma ń wáyé látara mímu ọtín àmupara.

Àwọn ohun míràn tí ó lẹ̀ sokùnfa ewu àìsàn ẹ̀dọ̀ jẹ́ ààrùn ìtọ̀ sugar, sísanrajù, ẹ̀jẹ̀ ríru, àti cholesterol gíga.

Dókítà Joanah Ikobah jẹ́ olùgbaninímọ̀ràn paediatric gastroenterologist, hepatologist àti olùkọ́ àgbà ní yunifásitì ìlú Calabar ní orílèḍè Nàìjíríà. Ó sọfún Africa Check wípé a kò lè sọ wípé ènìyàn ni àìsàn ẹ̀dọ̀ ọlọ́ọ̀rá púpọ̀ tàbí àìsàn ẹ̀dọ̀ míràn nípa wíwo bí ikùn rẹ̀ ṣe tóbi tó.

Ikobah soṕe, a lè fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé ènìyàn ní àìsàn ẹ̀dọ̀ lẹ́yìn ìgbà tí a bá sàyẹ̀wò lóríṣiríṣi, bii fífi ẹ̀rọ sàyèwò inú, àyèwò ẹ̀jẹ̀ àti fífi ẹ̀rọ sàyèwò ẹ̀dò.

Àwọn àyẹ̀wò míràn tó ní ṣe pẹ̀lú wíwo inú lójúkojú bíi liver biopsy àti magnetic resonance elastography.  

“Àṣìsọ ni láti ṣo wípé ènìyàn ní àìsàn ẹ̀dọ̀ ọlọ́ọ̀rá púpo tàbí àìsàn ẹ̀dọ̀ míràn nípa wíwo bí ikùn rẹ̀ ṣe tóbi tó,” Ikobah sọ fún wa. “Bó ti lè jẹ́ pé àìsàn ẹ̀dọ̀ ọlọ́ọ̀rá púpọ̀ lè ní ṣe pẹ̀lú sísanrajù, àwọn ènìyàn tí kò sanra náà lè ní àìsàn yìí.”

Ó fikun wípé ìtọ́jú fún onírúurú àìsàn ẹ̀dọ̀ dálórí àbájáde àyẹ̀wò rẹ̀.

A lè fìdí rẹ̀ múlẹ̀ wípé ènìyàn ní àìsàn ẹ̀dọ̀ ọlọ́ọ̀rá púpọ̀ tàbí irú àìsàn ẹ̀dọ̀ míràn lẹ́yìn tí a bá ṣe àyèwò lóríṣiríṣi. Àwọn ènìyàn tí ó bá yọkùn lè má ní àìsàn ẹ̀dọ̀ bẹ́ẹ̀ sìni àwọn ènìyàn tí kò yokùn lè ní àìsàn ẹ̀dọ̀.

 

Republish our content for free

We believe that everyone needs the facts.

You can republish the text of this article free of charge, both online and in print. However, we ask that you pay attention to these simple guidelines. In a nutshell:

1. Do not include images, as in most cases we do not own the copyright.

2. Please do not edit the article.

3. Make sure you credit "Africa Check" in the byline and don't forget to mention that the article was originally published on africacheck.org.

For publishers: what to do if your post is rated false

A fact-checker has rated your Facebook or Instagram post as “false”, “altered”, “partly false” or “missing context”. This could have serious consequences. What do you do?

Click on our guide for the steps you should follow.

Publishers guide

Africa Check teams up with Facebook

Africa Check is a partner in Meta's third-party fact-checking programme to help stop the spread of false information on social media.

The content we rate as “false” will be downgraded on Facebook and Instagram. This means fewer people will see it.

You can also help identify false information on Facebook. This guide explains how.

Add new comment

Restricted HTML

  • Allowed HTML tags: <a href hreflang> <em> <strong> <cite> <blockquote cite> <code> <ul type> <ol start type> <li> <dl> <dt> <dd> <h2 id> <h3 id> <h4 id> <h5 id> <h6 id>
  • Lines and paragraphs break automatically.
  • Web page addresses and email addresses turn into links automatically.
limit: 600 characters

Want to keep reading our fact-checks?

We will never charge you for verified, reliable information. Help us keep it that way by supporting our work.

Become a newsletter subscriber

Support independent fact-checking in Africa.