Back to Africa Check

Ààrẹ orílẹ̀dè Nàìjíríà, Bọ́lá Tinubú kò pàrọ̀ naira pẹ̀lú dollar, wọ́n ti sarúmọjẹ nínú fídíò tí ó ń kákìri tí ó sọ èyí

NÍ ÈDÈ KÚKÚRÚ: Ní ọdún 2023, Naira tí ó jẹ́ owó tí wọ́n ná ní orílẹ̀dè Nàìjíríà kojú àwọn ìpèníjà loríṣiríṣi, léyìí tí àìsíowó àti bí ó ṣe já wálẹ̀ ní ọjà àgbáyé.  Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ pé ààrẹ Bola Tinubu ti fi dollar rọṕò naira jẹ́ irọ́ póńbélé.

 

Ní ọdún 2022, ni wọ́n ṣe àtúntẹ̀ naira ní ìgbìyànjú láti kọjú ìjà sí títẹ owó ayédèrú àti ìṣẹrùbàlú, léyìí tó sokùnfa bí àìsíowó ní oṣù keji ọdún 2023. 

Lẹ́yìn tí Naira bẹ̀rẹ̀ sí ní dínkù níye ní ọjà àgbáyé ní kíákíá, àti pé ní akitiyan láti mú kí iye rẹ̀ má túbọ̀ lọlẹ̀ si, ààrẹ Bola Tinubu ní kí wọ́n ma pàrọ̀ owó ilẹ̀ òkèèrè sí ti orílẹ̀dè Nàìjíríà ní iye kan náà. 

Láìpẹ́ yìí, wàhálà ọ̀rọ̀ pípàrọ̀ owó ilẹ̀ òkèèrè sí ti ilẹ̀ yìí túbọ̀ peléke síi, bí iye naira sí àwọn owó ilẹ̀ míràn ṣe ń dínkù síi. 

Ní ìdí èyí ni fídíò kan tí ó ń káàkiri lóri Facebook ní orílẹ̀dè nàìjíríà ṣe ń ṣo pé Tinubu ní ìpinu láti yí owó orílẹ̀dè yìí sí dọ́là. 

Àkọ̀rí fídiò òhún kà báyìí: “Nàìjíríà ń pinu láti fòpin sí lílo naira tí wọn sì fẹ́ bẹ̀rẹ̀ síní ná dọ́là. President Tinubu ló sọ báyìí. Ìránṣẹ́ lásán ni èmi jẹ́, ẹ má pa ìránṣẹ́.

Ọ̀rọ̀ yìí jáde lórí Facebook ní ibí, ibí àti ibí. 

Ṣùgbọ́n ṣé fídíò òhún ń fihàn pé Tinubu ń sọ ìpinu rẹ̀ láti yí owó orílẹ̀dè náà padà sí dọ́là? A ṣèwamdìí. 

NairaDollar_False

Wọ́n ti yí ọwọ́ padà lórí fídíò kárí ilé yìí 

Nínú fídiò yìí ni Atọ́kun Arise News kan Ojy Okpe wà, ìparí rẹ̀ ní ibi tí ààrẹ ti ń sọ wípé orílẹ̀dè náà yíò pa naira tì fún dòlà ni ó dàbí enipé wọ́n ti sarúmọjẹ sí. 

Bí ètè atọ́kùn ọ̀hún àti ti àarẹ ṣe ń jì kò bá ohùn tí ó ń jáde láti inú fídíò ọ̀hún mu. 

Bákan náà, Arise News ti fi ọ̀rọ̀ léde lórí orúkọ ìdánimọ̀ rẹ̀ lórí X ( tí a mọ̀ sí Twitter tẹ́lẹ̀rí), ó sọpé fídíò yìí jẹ́ iṣéọwọ́ àwọn tí ó ma ń tẹ ìròyìn èké ránṣẹ́,” tí ó sì fi síkírínsọọ̀tì fídíò òhún tí a fi òǹtẹ̀ “FAKE” lù. 

Ọ̀rọ̀ tí wọn fi léde òhún kà báyìí: Arise News ti ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ lára fídíò tí ó ń káàkiri lórí àwọn òpó ìkànsíaraẹni tí ó ń farawé “Ojy Okpe atọ́kùn ètò What's Trending”.

A tẹ̀síwájú si nínú ìwádìí wa, ṣùgbọ́n a kòrí ìròyìn kankan láti ọwọ àwọn ilé-iṣé oníròyìn tí ó dántọ́ ní ilẹ̀ yìí àti ti òkèrè tí ó gbé ọ̀rọ̀ látẹnu ààrẹ lórí ọ̀rọ̀ yìí. Tí ó bá jẹ́ wípé òótó ni ọ̀rọ̀ náà yíò ti jáde gẹ́gẹ́ bíi àkọ́lé ìròyìn lóríṣiríṣi ọ̀nà. 

Ka ìtọ́nisọ́nà wa lórí bí o ṣe lè dá àwọn fídíò èké, tàbí èyí tí ohùn tí ó wà nínú rẹ̀ kò bá ohun tí wó ń ròyìn rẹ̀ mu kí o lè dá wọn mọ̀, kí o má sì ba gbà wọ́n gbọ́ nítorí àìkíyèsára. 

 

Republish our content for free

We believe that everyone needs the facts.

You can republish the text of this article free of charge, both online and in print. However, we ask that you pay attention to these simple guidelines. In a nutshell:

1. Do not include images, as in most cases we do not own the copyright.

2. Please do not edit the article.

3. Make sure you credit "Africa Check" in the byline and don't forget to mention that the article was originally published on africacheck.org.

For publishers: what to do if your post is rated false

A fact-checker has rated your Facebook or Instagram post as “false”, “altered”, “partly false” or “missing context”. This could have serious consequences. What do you do?

Click on our guide for the steps you should follow.

Publishers guide

Africa Check teams up with Facebook

Africa Check is a partner in Meta's third-party fact-checking programme to help stop the spread of false information on social media.

The content we rate as “false” will be downgraded on Facebook and Instagram. This means fewer people will see it.

You can also help identify false information on Facebook. This guide explains how.

Add new comment

Restricted HTML

  • Allowed HTML tags: <a href hreflang> <em> <strong> <cite> <blockquote cite> <code> <ul type> <ol start type> <li> <dl> <dt> <dd> <h2 id> <h3 id> <h4 id> <h5 id> <h6 id>
  • Lines and paragraphs break automatically.
  • Web page addresses and email addresses turn into links automatically.
limit: 600 characters

Want to keep reading our fact-checks?

We will never charge you for verified, reliable information. Help us keep it that way by supporting our work.

Become a newsletter subscriber

Support independent fact-checking in Africa.