Back to Africa Check

Rárá, ogun láarin orílèdè Russia àti Ukraine kò sokùnfa ọrọ̀ ajé tó dẹnu kọlẹ̀ ní UK, dúnàdúrà epo bẹtrióò pèlú orílèdè Nàìjíríà

Àtẹ̀ránṣẹ́ kan tí ó ń tàn yíká lórí Facebook sopé ogun tí ó bẹ́ sílẹ̀ ní orílẹ̀dè Ukraine ti mú kí ọrọ̀ ajé dẹnu kọlẹ̀ ní UK. Ó ṣàfikún wípé adarí ìgbìmọ̀ ìjọba ti Britain, Boris Johnson ń bá àwọn orílẹ̀dè tí ó wà ní àárín ìlà-oòrùn  àti orílẹ̀dè Nàìjíríà dúnàdúrà- ‘láti gbógun ti wàhálà ọ̀rọ̀ epo bẹtiróò tí ó túbọ̀ n peĺeke sii’

Àtẹ̀ránṣẹ́ náà kà báyìí  “ ọrọ̀ ajé dẹnu kọlẹ̀ ni Britain, Ogun bẹ́ sílẹ̀ ní Ukraine. Boris n dúnàdúrà pelu àwọn orílẹ̀dè tí ó wà ní àárín ìlà-oòrùn láti dáàbò bo Britain lóri wàhálà òrò epo bẹtiróò tí ó túbọ̀ n peĺeke sii’. Fún ìdí tí ó jẹmọ́  ètò ọrọ̀ aje ́ àdàpọ̀ Ilé-iṣẹ́ GB yíì ó bá oŕilèdè Nàijíríà ṣiṣẹ́ pọ̀ láti mójú tó ọrọ̀ ajé epo rọ̀bì àti láti dékun wàhálà tí ó  wà ní iĺẹ̀ Biafra.”

Ọjọ́ tí a kọ́kọ́ tẹ̀ránsẹ́ ni ọjọ́ kọkànlélógún oṣù kẹ́ta ọdún 2022, ìgbà 647 ó lé ni ẹlòmíràn ti tẹ̀ránsẹ́.

Biafra jẹ́ atọ́ka apá guúsù ilà-oòrùn orílèdè Nàijíríà níbi t́i awuyewuye fún ìbọ̀sí̀po ìjọba olómìnira ti Biafra ti ń wáyé. Ìjọba olómìnira ọ̀hún gbinlẹ̀ láàrín ọ̀dún 1967 sí 1970 léyìí tí ó sokùnfa ogun abélé ní orílèdè Nàijíríà.

Ṣùgbọ́n ṣé ọrọ̀ ajé dẹnu kọlẹ̀ ní UK? Àti wípé ǹjé wàhálà tí ó ń bẹ lórílẹ̀dè Ukraine ṣokùnfa kí Britain ó ma wojú orílẹ̀dè Nàijíríà fún epo betiróò?

Ukraine Petrol

Títí di oṣù kẹ́ta ọdún 2022, ọrọ̀ ajé kò dẹnu kọlẹ̀ ní UK

Ní ìlànà gbèndéke ti àjo International Monetary Fund (IMF) gbékalẹ̀ a lè sọpé ọrọ̀ ajé dẹnu kọlẹ̀ ní orílèdè kan tí ojúlówó àpapọ̀ iye ọrọ̀ ajé abélé rẹ̀ léyìí tí ó ti ni àfíkún-àtúnṣe bá wá lẹ̀ ní ipele méjì tèlé ra wọn nínú ìdásímérin ọdún.

Títí di oṣù kẹ́ta 2022, kò sí ẹ̀rí tó jágbangba wípé ọrọ̀ ajé dẹnu kọlẹ̀ ní Britain.

Ìṣirò tí ó jẹ́ tàìpé ni èyí tí ọ́fíìsì tí ó ń rísí ìsirò ní orílẹ̀dè ẹ̀ka ti UK gbé síta ní oṣù kínní ọdún 2022. Ní osù náà 0.8% ni ètò ọrọ̀ ajé abélé wọn fi dàgbàsókè. Ọjọ́ kọkànlá oṣù kẹ́rin ni ọ́fíìsi náà pinu láti ṣe àtẹ̀jáde ìsirò ti oṣù kejì.

Àgbéyèwò kan tí àjọ IMF ṣe ní ìparí oṣù kejì ni ó fihàn wípé ìbòsípò ètò ọrọ̀ ajé UK láti ìgbà àjàkálẹ̀ àrùn Covid àti ìgbà tí wọ́n ti fi ẹgbẹ́ European Union sílẹ̀ ni ó yá ju bí wọ́n ti lérò lọ. Àbájáde ìdàgbàsókè ọ̀hún lágbára gan ni.

Ilé-iṣẹ́ National Institute of Economic and Social Research ti UK ní oṣù kẹ́ta wòye pé ọrọ̀ ajé orílèdè náà lè dẹnu kọlẹ̀ ní ìdajì ọdún 2022 tí iye owó epo bá ṣì wà ní iye tí ó wà lọ́wọ́. Ilé-iṣẹ́ náà sọpé “ó seése kí ọrọ̀ ajé wọn má denu kọlè tí wọ́n bá sàgbékalẹ̀ ètò ìmúlò owó àti owó níná tí kò nira púpọ̀”.

Adarí ìgbìmọ̀ ìjọba ti ń wọ́nà àtúnṣe míràn sí wàhálà ọ̀rọ̀ epo

Orísirísi ìròyìn ni ó jáde nípa ìgbìyànjú Johnson láti bá àwọn orílẹ̀dè tí ó wà ní àárín ìlà-oòrùn dúnàdúrà epo, lẹ́yìn wàhálà epo tí ó wáyé látàrí bí Russia ṣe kógun ja Ukraine.

Sùgbọ́n a kòri èrí wípé adarí ìgbìmọ̀ ìjọba náà gbìyànjú láti dúnàdúrà pẹ̀lú orílèdè Nàìjíríà.

Ọrọ̀ ajé kò dẹnu kọlẹ̀ ní Britain, títí di oṣù kẹ́ta ọdún 2022. Bí ó ti lẹ̀ jẹ́pé Johnson lè ní ǹkan ṣe pẹ̀lú àwọn orílẹ̀dè tí ó wà ní àárín ìlà-oòrùn a kòrí ohunkóhun tí ó so èyí pọ̀ mọ́ orílèdè Nàìjíríà tàbí àwọn ìsẹ̀lẹ̀ tí ó ń wáyé ní apá gúúsù ìlà-oòrùn orílèdè Nàìjíríà.

 

Republish our content for free

We believe that everyone needs the facts.

You can republish the text of this article free of charge, both online and in print. However, we ask that you pay attention to these simple guidelines. In a nutshell:

1. Do not include images, as in most cases we do not own the copyright.

2. Please do not edit the article.

3. Make sure you credit "Africa Check" in the byline and don't forget to mention that the article was originally published on africacheck.org.

For publishers: what to do if your post is rated false

A fact-checker has rated your Facebook or Instagram post as “false”, “altered”, “partly false” or “missing context”. This could have serious consequences. What do you do?

Click on our guide for the steps you should follow.

Publishers guide

Africa Check teams up with Facebook

Africa Check is a partner in Meta's third-party fact-checking programme to help stop the spread of false information on social media.

The content we rate as “false” will be downgraded on Facebook and Instagram. This means fewer people will see it.

You can also help identify false information on Facebook. This guide explains how.

Add new comment

Restricted HTML

  • Allowed HTML tags: <a href hreflang> <em> <strong> <cite> <blockquote cite> <code> <ul type> <ol start type> <li> <dl> <dt> <dd> <h2 id> <h3 id> <h4 id> <h5 id> <h6 id>
  • Lines and paragraphs break automatically.
  • Web page addresses and email addresses turn into links automatically.
limit: 600 characters

Want to keep reading our fact-checks?

We will never charge you for verified, reliable information. Help us keep it that way by supporting our work.

Become a newsletter subscriber

Support independent fact-checking in Africa.