Back to Africa Check

Rárá, Wọn kò yọ ààrẹ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà ti orílẹ̀dè Nàìjíríà, Godswill Akpabio nípò

NÍ ÈDÈ KÚKÚRÚ: Gẹ́gẹ́ bí àwọn àtẹránṣẹ́ kan lórí Facebook ṣe sọ, wọn ti yọ ààrẹ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà ti orílẹ̀dè Nàìjíríà nípò. Èyí kìí ṣe òótọ́ àti pé ẹ kọtí ikún sí àwọn àtẹ̀ránṣé orí àwọn òpó ìkànsíaraẹni tí ó ń sọ pé wọ́n ti yọ nípò. 

 

Fídíò kan tí wón gbé sórí Facebook ní ó ń sọ pé wọ́n ti yọ ààrẹ ilé ìgbìmọ̀ asòfin àgbà ti orílẹ̀dè Nàìjíríà nípò. 

Ọkùnrin tí ó ń sọ̀rọ̀ nínú fídíò náà sọpé inú òhun dùn sí ìròyìn náà tí ó sì ń sọ fún àwọn èèyàn láti tẹ àtẹ̀ránsẹ́ ọ̀hún sí àwọn elòmíràn. 

Fídíò ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù kẹsan ọdún 2023 òhún ni àkólé rẹ̀ kà báyìí: “Àwọn ọmọ ilé ìgbìmọ̀ asòfin àgbà bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ láti yọ ààrẹ ilé ìgbìmọ̀ asòfin àgbà Akpabio nípò nítorí bí ó ṣe ń ṣe ìfé Tinubu léyìí tí ó ye kí ó máa sin àwọn ará ìlú…”

Ìyọnípò jé ìgbéṣè tí wọ́n ń gbà yọ ààre tàbí òṣìṣẹ́ ìjọba àgbà kan nípò tí wọ́n bá fi ẹ̀sùn ọ̀daràn kàn wọ́n.

Fídíò náà ni ó lé ní ọgọrun lọ́nà ẹgbẹ̀rún èèyàn ti wò, tí ó lé ní ẹgbẹ̀rún sì ti sọ tẹnu wọn lórí rè. 

Àwọn àtẹ̀ránṣé tí ó jẹ́ irúfẹ́ èyí ni a rí ní ibí, ibí àti ibí.

Ṣùgbọn ṣé wọ́n ti yọ Akpabio nípò? A ṣèwádìí. 

AkpabioImpeached_False

Ààrẹ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà já iró òhún

Wọ́n dìbò yan Akpabio gẹ́gẹ́ bí ààrẹ ilé ìgbìmò aṣòfin àgbà ìkẹ́wa ní ọjọ́ ketàlá oṣù kẹfà ọdún 2023. Lẹ́yìn tí wọ́n ti dìbò yàán, àwọn ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà kan ni wọ́n sọ pé wọ́n gbìmọ̀ pọ̀ láti yọ́ kúrò nípò, nítorí pé kò kújúwọ̀n láti ṣe iṣé náà.

Olùgbani nímọ̀ràn rẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ ìgbéìròhìnjáde, Eseme Eyiboh, ni ó ko òrò náà dànù tí ó sọ pé “kò ní òótọ́ nínú”.

Ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà náà ti sọpé irọ́ ni ìròyìn ìyọnípò náà, tí ó sì sọ wípé Akpabio kújúwòn láti dipò náà mú. 

 

Republish our content for free

We believe that everyone needs the facts.

You can republish the text of this article free of charge, both online and in print. However, we ask that you pay attention to these simple guidelines. In a nutshell:

1. Do not include images, as in most cases we do not own the copyright.

2. Please do not edit the article.

3. Make sure you credit "Africa Check" in the byline and don't forget to mention that the article was originally published on africacheck.org.

For publishers: what to do if your post is rated false

A fact-checker has rated your Facebook or Instagram post as “false”, “altered”, “partly false” or “missing context”. This could have serious consequences. What do you do?

Click on our guide for the steps you should follow.

Publishers guide

Africa Check teams up with Facebook

Africa Check is a partner in Meta's third-party fact-checking programme to help stop the spread of false information on social media.

The content we rate as “false” will be downgraded on Facebook and Instagram. This means fewer people will see it.

You can also help identify false information on Facebook. This guide explains how.

Add new comment

Restricted HTML

  • Allowed HTML tags: <a href hreflang> <em> <strong> <cite> <blockquote cite> <code> <ul type> <ol start type> <li> <dl> <dt> <dd> <h2 id> <h3 id> <h4 id> <h5 id> <h6 id>
  • Lines and paragraphs break automatically.
  • Web page addresses and email addresses turn into links automatically.
limit: 600 characters

Want to keep reading our fact-checks?

We will never charge you for verified, reliable information. Help us keep it that way by supporting our work.

Become a newsletter subscriber

Support independent fact-checking in Africa.